Ìbúgbàmù Bódìjà! Mákindé buwọ́lu ₦4.08b fún àwọn tó pàdánù ẹ̀mí àti dúkìá wọn

Ìbúgbàmù Bódìjà! Mákindé buwọ́lu ₦4.08b fún àwọn tó pàdánù ẹ̀mí àti dúkìá wọn

Fẹ́mi Akínṣọlá

Oṣù méjìdínlógún lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ ìbúgbàmù ńlá tó wáyé ní agbègbè Bódìjà, nílùú Ìbàdàn, àwọn kan lára àwọn tó pàdánù dúkìá àti mọ̀lẹ́bí wọn ti bẹ̀rẹ̀ sí í gba owó ìràn lọ́wọ́ láti ọ̀dọ̀ ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.

Agbenusọ fun ẹgbẹ awọn olugbe Bodija Estate, Alufaa Muyiwa Bamgbose lo fidi iroyin naa mulẹ nibi ipade awọn akọroyin ti wọn ṣe ninu gbagede Pentorise, to wa ni Bodija nílùú Ìbàdàn.

Bamgbose ṣalaye pe ₦4.08 biliọnu ni ijọba ipinlẹ Oyo buwọlu gẹgẹ bii owo iranwọ fun awọn to lugbadi nigba ti ibugbamu naa sẹlẹ.
Eeyan maarun lo padanu ẹmi wọn nibẹ, ti ọkọ ayọkele mẹtadinlogoji si ba a lọ.

Iṣẹlẹ naa tun sọ eeyan mejilelọgọrun di alainilelori.

Alufaa Bamgbose sọ pe o le ni milliọnu marundinlogoji naira ti awọn ẹlẹyinju aanu fi ranṣẹ lati ṣeranwọn fun awọn to lugbadi nibi iṣẹlẹ ọhun.

Ajọ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri ti ipinlẹ Oyo ati ti ijọba apapọ, NEMA naa tun fi awọn ohun elo idẹrun ọlọkan-o-jọkan ranṣẹ.

Bamgbose ni awọn olugbe Bodija ti fi ẹka kan lole ti yoo ṣe abojuto aabo, iwọlewọde ati amojuto agbegbe Bodija lati gbogun ti irufẹ iṣẹlẹ bẹẹ lọjọ iwaju.