Bola Afolabi
Yoruba ni aremaja kan ko si, sugbon owe yii ko fe sise lori ajose Aare Bola Tinubu ati okan pataki laarin awon ajumorin re tele, iyen Ogbeni Rauf Aregbesaola.
Ko to di nnkan odun bii mefa seyin, bi igbin fa ikarahun a tele e ni oro awon mejeeji je.
Tinubu nigbagbo ninu Aregbesola tele debi pe oun lo se komisanna oro ise (Commissioner for Works), ti o je ile ise ijoba nla, ni odun mejeejo ti Tinubu fi je gomina l’Ekoo, lodun 1999 si 2007.
Bi Aregbe tun se di gomina ni Ipinle Osun, nigba ti oju ogun tile le koko, atiranmu gangan ko seyin eekanna.
Tinubu ni opo gba pe o seto owo, ogbon oselu ati bee bee lo to je ki won ri knni naa ja gba lowo Omo Oba Olagunsoye Oyinlola, to je gomina labe asia egbe Peoples Democratic Party l’Osun nigba kan.

Ajosepo naa dun moranin-moranin ko to di pe tirela oselu gba aarin oga ati omoose re koja.
Ere ni, awada ni, oselu Osun da isu ata yan-an-yan-an sile, debi pe igba ti Tinubu gbe apoti ibo Aare ni 2022 si 2023, Aregbesola to ye ko je opa itile re akoko ko si leyin re bi aye se n reti.
Ohun ti Tinubu tabi eni to di gomina leyin re, iyen Adegboyega Oyetola, eni to je okan lara awon minisita Tinubu bayii, se fun un dun un debi wi pe Tinubu ko ri ibo to bi awon kan se lero to ni Ipinle Osun.
Koda, latigba to ti di Aare naa, Aregbe ko ri tie ka si dabi alara.
Dipo bee, leyin to se ore Gomina to gba ipo mo Oyetola lowo, Alagba Ademola Adeleke, oun ati alatako Tinubu akoko, Atiku Abubakar, ni won jo n doweke.
Bee, 2027 lo tun de tan yii, awon onwoye n beere pe se Aregbesola yoo sise fun alatako Tinubu ni?
Pelu bi inu se n bi i ni abidiju yii, etutu wo ni Tinubu fe se fun un ti inu ye yoo fi ro, boya gege bii baba si omo, tabi gege bii eni to ye ko maa korin ‘epo ni mo ru…’
Ese wo ni Tinubu se Aregbesola?
Bi o tile je pe awon mejeeji ko tii jokoo nita gbangba lati so ti enu won, awon atotonu kan ti n jade lotun-un, losi lori bi ofon-on se to si gbegiri.
Lona kinni, a gbo pe inu Aregbesola ko tete yo si bi Oyetola se gbe apoti ni Osun.
Oyetola, eni ti won pe ni aburo Tinubu, ni Tinubu fe, sugbon elomiran ni a gbo pe okan Aregbe yan.
Leyin-o-reyin, o n lati teriba fun oga re ni.
Eyi to tun so mo eyi ni pe Aregbe naa gba pe oun ti to baba isale oselu se, paapaa ni Osun, sugbon Tinubu kii fi eyi ba eniyan sere.
Se Yoruba ni oga meji kii gbe inu oko kan naa; ati pe bi baale ba di meji, itan eran a di pinpin.
Sugbon gege bi Aregbe se fi enu ara re so, iha ti Oyetola ko si ohun ati awon emewa re nigba to je gomina lo da surutu nla sile.
O ni bi oun ati awon eniyan oun se f’okan atara sise fun Oyetola to, o da awon nu bi omi isinwo ni.
O ni o so awon di eni aijiiri bi eepo egusi, leyin to yo dundun inu awon je tan.
Lati odo awon Oyetola, a gbo pe Aregbe fe gba awon ipo komisanna nla nla kan fun awon eniyan tie, sugbon Oyetola ni ko se e se bee.
Ohun ti Aregbe wa so lasiko to n ba awon omoleyin re soro ni pe awon ni adehun lori ipo ti Oyetola yoo yan awon eniyan oun si, ati lori awon oro asiri miran, sugbon Oyetola da awon ipinnu yii nu ni, gege bi Aregbe se so.
Bi tibi se n wi, ni t’oun n wi. Ohun to wa se pataki julo ni pe aarin won daru debi pe lasiko ibo Adeleke ati Oyetola, ti Adeleke ni Aregbe se.
Nipa idi eyi, Oyetola kuna lati pada si ipo.
Idi niyi ti oro fi di nanto, tori o ti di fifi oro ya oro.
O se je pe Aregbe ko le se bi Ambode tabi Sanwo-Olu?
Yoruba tun bo won ni a ko ri iru eleyii ri, a fi n deru ba oloro ni.
To ba je pe ki ede aiyede wa laarin Tinubu ati awon emewa re, t’oun ati Aregbe kii se akoko.
Koda, omo tuntun kii se akopa aje ni.
Aimoye ni awon komisanna re tele ti won ba Tinubu y’odi nigba ti ko fi won se gomina.
Ni pabambari, Tinubu gba tikeeti sonu lowo Gomina Eko tele, Akinwunmi Ambode, nigba ti nnkan daru laarin won.
Laipe yii ewe, o gbena woju Gomina Babajide Sanwo-Olu, eni to fun ni tikeeti to gba kuro lowo Ambode.
Ohun to tun wa se pataki ni pe, lonii, gbogbo awon ti a daruko loke yii ni won tun ti di wole-wode pelu Tinubu.
O se wa je ti awuyewuye oun ati Aregbe wa di kaka ki eku ma je sese?
Loooto, isele laarin oun ati awon ti a ka sile yii yato si t’oun ati Aregbe.
Bi apeere, oro Oyetola, eni to je komisanna Aregbe tele, je ohun to jo pe o n dun Aregbe ju.
Didari egbe APC l’Osun naa, nnkan nla to mu iyato ba ikunsinnu ti iru Ambode ni pelu Tinubu ni.
Aregbe ni ‘la’, o doodi! Ko ye ki baba so pe o di owo omo oun lorun.
Kaka ki kinniun se akapo ekun, ki koowa se ode tie lotooto ni.
Idi niyi ti awon amoye oselu fi gba pe afaimo ni ki surutu to wa nile naa ma wa titi di 2027.
Sibesibe, opo naa lo gbagbo pe oore ti Tinubu ti se fun Aregbesola po ju ki o wa sise fun ota re lo – iyen ota Tinubu.
Igbagbo won ni pe ati ranmu gangan, ko seyin eekanna.
Won ni bi Tinubu ko ba fi Aregbe se komisanna l’Ekoo ni, ko wule ni wa nipo to wa bayii lati maa ba a ta kan-n-gbon.

Bakan naa, won ni ese yowu to ye ki Tinubu se e , o ye ko ro ti atimaabo won; to si je pe bi a ba ni ka wo didun ifon, a o hora de eegun.
Sugbon eyi ko tumo si pe ki awon Tinubu ati Oyetola naa ma se ohun to ye ki won se fun Aregbe, tori eleran ara ni gbogbo wa.
Se ‘Gba fun Raaji’ ni ‘Gba fun Gbada’. Ara oko ti yoo je buredi, a foguso ranse sile.
Bi won ko tie ro gbogbo nnkan, o ye ki won ranti pe ibo ti Aregbe le fe ko fun awon Atiku l’Osun le di ohun ti yoo yi awon l’agbo da sina.
Bee, ebe laa be osika.
Owe ni IROYIN OWURO fi pa o. A ko pe Aregbe ni Fadeyi Oloro!