Ìṣẹ̀lẹ̀ Ibom Air dójú ti mí, n kò lè jáde mọ́ nínú ilé, gbogbo ayé ló ń fi ara mi ṣe ‘sticker’ – Comfort Emmanson
Fẹ́mi Akínṣọlá
Comfort Emmanson ti sọ̀rọ̀ sókè fún ìgbà àkọ́kọ́ lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ tó wàyé láàrin rẹ̀ àtàwọn òṣìṣẹ́ iléeṣẹ́ ọkọ̀ òfurufú Ibom Air.
Ọjọ kẹwaa, oṣu Kẹjọ ti a wa yii ni iṣẹlẹ naa waye ni papakọ ofurufu ilu Eko, lẹyin eyii ti wọn gbe lọ sile ẹjọ to si di ẹni to n sun atimọle ọgba ẹwọn mọju.
Ninu fidio to fi lede loju opo Instagram rẹ, ọdọbinrun ọhun dupẹ lọwọ awọn ololufẹ rẹ atawọn ọmọ Naijiria fun atilẹyin wọn, lẹyin naa lo ṣalaye ohun to ṣẹlẹ ni kikun ni iha tirẹ.
Gẹgẹ bii Comfort ṣe ṣalaye, wahala naa bẹrẹ ni kete ti wọn gbera kuro ni papakọ ofurufu ilu Uyo lọ ilu Eko ti ọkan lara awọn oṣiṣẹ inu baalu naa, Juliana, sọ fun oun pe ki oun pa foonu oun.
Comfort ni bọtitini ọkan lara awọn foonu oun ko dara, eyii to mu ko ṣoro fun oun lati pa foonu naa.
O ni “Mi o kọ lati pa foonu mi o, mo sọ fun pe bọtini ti mo fi n pa foonu naa ko dara, mo si nilo iranlọwọ lati pa a amọ o kọ jalẹ.
“Arinrinjo mii to joko lẹgbẹ mi lo pada ran mi lọwọ lati pa foonu mejeji ọwọ mi.”
O ni lẹyin ti oun pa awọn foonu naa tan ni Juliana dunkoko mọ oun pe oun yo fi oju oun ri mabo.
Ninu alaye rẹ, lẹyin ti wọn de ilu Eko, Juliana yii kan naa kọ lati jẹ ki oun jade ninu baalu, to si n fi oju buruku wo oun.
Comfort sọ pe gbogbo igbiyanju ati ẹbẹ oun lati jẹ ki Juliana fi oun silẹ, ki oun si jade kuro ninu baalu naa lo kọ eti ọgbọin si.
O ni nigba ti oun ri pe ọrọ naa le di yanpọnyanrin loun tan foonu oun pada ti oun si bẹrẹ si n ka ohun o n waye silẹ.
O tẹsiwaju pe “Juliana yii fa irun ti mo de sori, o ja ẹgba ọrun mi to jẹ wura, asiko to n ṣe eyii ni foonu mi jabọ, ti foonu naa si fọ.
Nigba to n tẹsiwaju, o ni asiko wahala naa ni pupọ awọn oṣiṣẹ baalu yabo oun, ti wọn si n fi agidi wọ oun jade ninu baalu ọhun.
Comfort ni asiko ti wọn n wọ oun jade ninu ọkọ ofurufu naa ni Juliana fa aṣọ oun ya, ti gbogbo ọyan oun si tu jade.
O sọ pe “bi wọn ṣe n wọ mi jade, lo fa aṣọ mi ti aṣọ naa si ya.
“Gbogbo wọn bẹrẹ si n ya fidio mi bo tilẹ jẹ pe aṣọ mi ti faya, gbogbo aye lo ti ri ara mi bayii, koda awọn mii ti fi ara mi ṣe ‘sticker’ bayii.
Comfort ni “Ohun ti wọn ṣe fun mi yẹn ti pọju fun mi, mi o le fara da a.
“Bi mo ṣe n ba yin sọrọ yi, mi o le jade sita mọ nitori gbogbo aye lo ti ri ara mi. Oju n ti mi lati jade si igboro.
“Isẹ kara-kata ilẹ ati ile ni mo n ṣe, ẹyin naa ẹ wo o, ti mo ba fẹ ta ilẹ fun eeyan bayii, ti mo lọ ba awọn onibara, ara mi ni wọn n wo.”
Ọdọbinrin ọhun ni oju n ti oun lati jade sita latari pe ọpọ eeyan kaakiri agbaye lo ti mọ oun, to si jẹ pe oju ihoho oun to ti wa nita wọn fi n wo oun.
Lẹyin naa lo ni oun kii ṣe oni jagidijagan eeyan, ohun kii ṣii ṣe ẹni to maa ri agbalagba bii Juliana fin, amọ niṣe ni obinrin naa atawọn akẹgbẹ rẹ mọọmọ da sẹria fun oun lọna atiọ.
Ẹwẹ, Comfort ti pe ileeṣẹ Ibom Air, ijọba apapọ ati ajọ to n ri si irinajo ọkọ ofurusu ni Naijiria lẹjọ lori iṣẹlẹ naa.
O ni gbogbo wọn gbọdọ san 500bn fun oun fun bi wọn doju ti oun, ti wọn si fi iya jẹ oun lọna aitọ.