Iṣẹ́ tíátà ni kò jẹ́ kí n kàwé – Ibrahim Chatta
Fẹ́mi Akínṣọlá
Gbajúmọ̀ òṣèré sinimá ti ilúmọọka jákèjádò àgbáyé ni Ibrahim Chatta. Gẹ́gẹ́ bí ó ṣe sọ nínú ifọrọwanilẹnuwo yìí, Ọmọ Tapa ni bàbá rẹ̀, ìyá rẹ̀ sì wá láti ìlú Mọdakẹkẹ ni ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun.
Gẹ́gẹ́ bí ọrọ̀ rẹ̀, ó ní láti kékeré lòun ti mọ pé iṣẹ́ òṣèré tíátà lòun yóó ṣe jẹun, láti ìgbà náà wá lòun sì ti gbájúmọ́ ní ṣàn án.
Ibrahim Chatta ni Iṣẹ tiata ti gba ọpọlọpọ nnkan sọnu lọwọ oun. Lara rẹ si ni lilọ si ile ẹkọ.
O ni lọpọ igba nigba ewe oun lawọn obi oun maa n ro wi pe ile ẹkọ loun wa, amọṣa to jẹ wi pe ode ere loun morile.
“Awọn obi mi maa n ro pe ile ẹkọ ni mo wa, ṣugbọn mo ti tẹle awọn onitiata lọ nitori mo maa n ṣe ere tiata alarinjo nigba naa.”
Gẹgẹ bi ọrọ rẹ, iṣẹ are to wa nigba naa ni Arinjo eyi tawọ oyinbo n pe ni, “Travel Theater” ki ere to yirapada si sinima to wa lode oni.
“Mi o pari ileẹkọ girama, mi o ni iwe ẹri iwe mẹwaa ṣugbọn mo n ṣe eto ẹkọ agbelegboye.”
Gbajumọ elere itage naa tun ṣalaye pe funra oun loun kọ ara oun ni ede oyinbo bẹẹni ko si iwe ti oun ko le ka.
Lọdun 1985, iyẹn ọdun mọkandinlogoji sẹyin, ni Ibrahim Chatta bẹrẹ iṣẹ ere tiata.
O ni nigba naa, nibikibi ti awọn ba gbe ere lọ, awọn a ti tete maa ba awọn ọmọ olounjẹ ati alata bẹẹbẹẹ dọrẹpọ nitori lasiko ti ebi ba n pa wọn, awọn wọnyi lawọn maa n gbara le lati ye niagba naa.
O ni gẹgẹ bi elere, eeyan gbọdọ mọ gbogbo nnkan nitori pe elere nilo ọpọlọpọ nnkan yala lerefe tabi ni ijinlẹ.
Ọpọ lo maa n wi pe, eekan onitiata yii ti yẹ ko ti gba ọpọ ami ẹyẹ ti awọn ti wọn wo pe wọn ko dangajia to lagbo oṣere ti gba.
Awọn ololufẹ Chatta a tilẹ maa sọ pe iye oriyin to n gba kere si ipa to ni lagbo oṣere lorilẹede Naijiria lọ.
O ni oun ko gbagbọ pe oun dara ju alare kan lọ nitori pe, gẹgẹbi ọrọ rẹ, “gbogbo alare ni maa n daa loju emi.”
O ni ọpọ awọn ami ẹyẹ ti wọn ti gbe kalẹ ti awọn ololufẹ oun maa n wo pe wọn o ti fun oun ni ami ẹyẹ ko dede ri bẹẹ, “emi ni mi o fi sinima mi silẹ fun ayẹwo ami ẹyẹ naa.”