Hèèmọ̀! Ọ̀dọ́bínrin kan kú sílé ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀ l’Ọ́sun, ọlọ́pàá bẹ̀rẹ̀ ìwádìí
Fẹ́mi Akínṣọlá
Ṣé àwọn àgbà sọ pé òwò tí àdá bá mọ̀ ní-ín ká àdá léyìn.
Ilé-iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun ti sọ fún akọ̀ròyìn pé àwọn ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí ikú tó pa ọ̀dọ́bìnrin Bidemi Omole nílé ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀ , Yinka, nílùú Ẹsa-Òkè n’ípìínlẹ̀ Ọ̀ṣun.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Osun, DSP Abiodun Ojelabi, lo fidi ọrọ yii mulẹ fun akọroyin lalẹ ana ọjọ Aiku ọjọ kẹrinlelogun oṣu Kẹjọ ti a wa yii.
Iṣẹlẹ naa ni a gbọ pe o ṣẹlẹ lalẹ ọjọ Ẹti to kọja nigba ti Bidemi de si ile Yinka.
Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Osun, DSP Abiodun Ojelabi, ṣalaye pe ”lalẹ ọjọ Ẹti to kọja ni Bidemi de si ile ọrẹkunrin rẹ, Yinka niluu Esa-Oke.
Yinka sọ fun wa pe o fẹ rẹ Bidemi diẹ lalẹ ọjọ naa, eyi lo si jẹ ki o maa bii.
Lẹyin naa ni Yinka sọ fun awa ọlọpaa wi pe oun atawọn eeyan kan gbe Bidemi digba digba lọ sile iwosan lati du ẹmi rẹ.
Amọ, Yinka sọ pe nile iwosan ti wọn gbe ọdọbinrin naa lọ lawọn dokita ti fidi rẹ mulẹ pe Bidemi ti jẹ Ọlọrun ni pe.”
DSP Ojelabi ko ṣai fidi rẹ mulẹ fun akọroyin pe Yinka to jẹ ọrẹkunrin Bidemi nikan ni afurasi tọwọ ọlọpaa ti tẹ bayii lori iku ọdọbinrin naa.
”Ọrẹkunrin Bidemi ti wa ni ahamọ wa, a si ti bẹrẹ iṣẹ iwadii lori ohun to ṣokunfa iku ọdọbinrin ọhun.”
Nigba ti akọ̀ròyìn beere lọwọ ọlọpaa bo ya Yinka yoo foju ba ile ẹjọ laipẹ, DSP Ojelabi ni ileeṣẹ ọlọpaa gbọdọ ṣe iwadii wọn tan lati mọ ohun to ṣokunfa iku Bidemi ki wọn to maa sọrọ gbigbe ọrẹkunrin oloogbe naa lọ sile ẹjọ.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa sọ pe laarọ ọjọ keji ọjọ Satide ọjọ kẹtalelogun oṣu Kẹjọ yii ni wọn to mu ẹjọ naa wa sọdọ awọn ọlọpaa lori iṣẹlẹ ọhun.
Ohun ti a tun gbọ ni pe Bidemi n mura lati lọ fun iṣọ-oru ni ṣọọṣi kan ni lasiko ti iṣẹlẹ ọhun waye.
DSP Ojelabi fikun ọrọ rẹ wi pe ileeṣẹ ọlọpaa yoo ṣayẹwo oku ọdọbinrin lati mọ ohun to ṣokunfa iku rẹ gan an.