Hèèmọ̀! Déọ̀rẹ́bà ẹni ọgọ́taọdúndíkan yà pa èèyàn méjì,nílùú Ìbàdàn
Fẹ́mi Akínṣọlá
Àwọn àgbà sọ pé ẹni orí bá kó yọ nìkan ló bọ́ nínú ewu èyí ló bí ìṣẹ̀lẹ̀ abámì kan tó rán èèyàn méjì s’ọ́run,nígbà tí ẹnìkan farapa yánayàna.
Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ló wáyé ní ojú-ọ̀nà Ọ̀jọ́ọ̀- sí Iwo Road nílùú Ìbàdàn.
Ìṣẹ̀lẹ̀ àgbọ́gbárímú yìí ló ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́rú ní nnkan bí aago méjìlá ọ̀sán, léyìí tó ya ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn tó wà lágbègbè ọ̀hún lẹ́nu.
Àwọn èèyàn tó kú ọ̀hún ni ọjọ́ orí wọn wà láàrin ọdún méjìlélógún sí ọdún mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n lá gbọ́n pé wọ́n n rìn lọ níbi tí awakọ̀ náà ti kọ lù wọ́n.
Àwọn kan tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣojú wọn sọ pé, wíwakọ̀ nílànà àìbìkítà ló mú kí ìṣẹ̀lẹ̀ náà la ẹ̀mí lọ.
Ojú ẹsẹ̀ tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà
ti détí ilé-iṣẹ́ ọlọ́pàá ni wọ́n ti tawọ́ gán dẹ́rẹ́bà tó pààyàn méjì ọ̀hún.
Ìròyìn òwúrọ̀ gbọ́ pé ẹnìkẹta tó farapa ti n gba ìwòsàn lọ́wọ́ nílé ìwòsàn kan tí wọn ò dáákọ.
Ìṣẹ̀lẹ̀ náà tó n ṣe
ọ̀pọ̀ àwọn tó ṣojú wọn ní
bàì bàì ni wọ́n ti n pè fún ìdájọ́ òdodo kò lè jẹ́ ẹ̀kọ́ fún gbogbo ẹni bá n wakọ̀ àìbìkítà lójú pópó.
Alukoro fún ilééṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ Adewale Osifeso ti fìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀ tó sì fi dá aráàlú lójú pé ilé-iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ kò ní dọwọ́ bo ọ̀rọ̀ náà, àti pé etí wọn kò ní di sí bó bá ṣe n lọ.