Hèèmọ̀! Àwọ̀n t’íṣà kan ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ rí kọ̀npútà ìkọ́ni t’íjọba ṣẹ̀ṣẹ̀ fún wọn bì èròjà ìwo fíìmù
Fẹ́mi Akínṣọlá
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé olóòtù ètò “ogún ọmọdé” gbóríyìn fún ìjọba lábẹ́ ìṣàkóso gómìnà Onímọ̀ ẹ̀rọ Oluseyi Makiñde niìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, fún àwọn akitiyan rẹ̀ lórí ètò ẹ̀kọ́, síbẹ̀ kò sàí mẹ́nuba àìlákàsì àwọn olùkọ́ kan tó jànfàní ẹ̀rọ ìkọ́mọ tuntun tí àwọn olùkọ́ ṣẹ̀ṣẹ̀ gbà ọ̀hún, pé fíímù àgbéléwò ni wọ́n kó sórí ohun èló tuntun ọ̀hùn fún wíwò .
Ṣùgbọ́n ní ìfèsì sí ọ̀rọ̀ olóòtú, àléjò orí ètò ogún ọmọdé Ògbẹ́niFẹ́miAkínṣọlá sì gbà pé ìgbà ọ̀tun ti dé báyìí fún àwọn olùkọ́ àti gbogbo akẹ́kọ́ọ̀ ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ bí ìgbésẹ̀ tuntun t’íjọba gbé kalè bá lọ bó ṣe yẹ.
Gbólóhùn òkè yìí ló bí
àmọ̀ràn tó lọ s’ọ́dọ̀ àwọn olùkọ́ ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ tí ìjọba ṣẹ̀ṣẹ̀ fún ní ìdánilẹ́kọ́ọ̀ lórí lílo ìmọ̀ ẹ̀rọ ìgbàlódé fún ìgbélárúgẹ ètò ẹ̀kọ́
láti rí i gẹ́gẹ́ bí ànfààní ọ̀tun tó lè mú àgbéga àti ìhùwàsí àwọn akẹ́kọ́ọ̀ yí padà sí rere dípò ó rírí bí
n bèbí ìléwó ọmọdé.
N ígbà tó n sọ̀rọ̀ níbi ìfọ̀rọ̀wérọ̀ ètò orí rádíò iléeṣẹ́ Fresh FM 106:6 àlejò pàtàkì lórí ètò náà tí wọ́n pè ní ogún ọmọdé tó máa ń wáyé ní Sátidé, láàrin aago mẹ́fà sí méje àṣálẹ́, èyí tí ògbóntarìgì àgbóhùnsáfẹ́ ọ̀hún ọmọọbá Abíọ́dún Lawal Agbólúajé dárí, ni ọ̀rọ̀ náà ti jẹyọ.
Àlejò pàtàkì ọ̀hún Ọ̀gbẹ́ni Fẹ́mi Akínṣọlá ṣàlàyé pé, ètò kíkọ́ ọmọ lẹ́kọ́ọ̀ ìwé lásìkò yìí tí fẹ́jú ju kí àwọn olùkọ́ sì tún máa di ìwé àkọsílẹ̀ ìlànà iṣẹ́ tàbí ìlànà àgbékalẹ̀ iṣẹ́ mọ́ àyà kiri.
Ó ní ìmọ̀ ẹ̀rọ òde òní ti ṣàwàrí gbogbo èròjà tí olùkọ́ nílò sójú kan ní àrọ́wọ́tó.
Ó tẹ̀síwájú pé ìdánilẹ́kọ̀ọ́ náà tí àwọn olùkọ́ tó ní ọjọ́ tó pọ̀ láti lò lẹ́nu iṣẹ́ ti kópa.
Àlejò orí ètò náà sọ pé, n tò lè jẹ́ kí ètò ìlànà tuntun náà ó nitumọ̀ kò ju bí àwọn olùkọ́ tó kópa níbi ìdánilẹ́kọ̀ọ́ náà bá ṣe já fáfá sí, nípa mímọ pàtàkì lílò rẹ̀.
Ó ní ìjáfáfá wọn ni yóó mú kí wọ́n lè lo ìmọ̀ ìgbàlódé náà tí wọ́n ní kọ́ àwọn ẹ̀ka ilé-ẹ̀kọ́ wọn jákèjádò ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ àti agbègbè rẹ̀ dípò fífi wo fíímù tó lè dá làákàyè wọn làámú tàbí kó kó wọn lọ́kàn sókè.
Bákan náà ló so pé àwọn tó kópa ìdálẹ́kọ̀ọ́ náà yẹ kí wọ́n lè fí kọ́ àwọn olùkọ́ tí kò ní ànfààní sí ìdánilẹ́kọ́ọ̀ ìmọ̀dọ̀tun yìí, bí bẹ́ẹ̀ kọ́ àwọ́n abala olúkọ́ tó lọ fún sẹ́mínà nìkan tó sì n lò ó déédé nìkan ni àwọn akẹ́kọ́ ọ̀ yóó jèrè wọn.
Èyí sì lè padà fa awuyewuye tàbí kí ìmọ̀ àwọn àkẹ́kọ̀ọ́ kan ó gọbọi ju tàwọn ẹ̀gbẹ́ wọn nínú ìṣedéédé ìmọ̀ sàájú ìlànà ìkọ́ni onímọ̀ ẹ̀rọ tábúlẹ́tì.
Ó ní ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ lábẹ́ àkóso onímọ̀ ẹ̀rọ Seyi Makinde gbọ́dọ̀ ri pé àwọn tó ṣagbátẹrù ètò ìlànà ìmò ẹ̀kọ́ ọ̀tun ọ̀hún mójútó bí èkọ́ ìlànà ìkọ́mọ tí àwọn olúkọ́ gbà náà yóó ṣé jẹ́ lílò fún ìgbà pípẹ́, bí wọ́n ṣe sọ pé àwọn olùkọ́ tó lọ́jọ́ púpọ̀ lẹ́nú iṣẹ́ ni kó jẹ́ ànfààní ọ̀hún.
Ó kádìí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé ,bí àmójútó bá wà, ìgbà ọ̀tun dé bá ètò ẹ̀kọ́ ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ nípasẹ̀ lílo tábúlẹ́tì ìkọ́mọníṣẹ́ àti kíkọ àwọn ohun tó jẹ mọ́ àyẹ̀wò fún akẹ́kọ́ọ̀ ,tó fi dórí àkọsílẹ̀ pàtàkì tó ní-ín ṣe pẹ̀lú akẹ́kọ̀ọ́.