Gómìnà Mákindé la Adelabu mọ́ iwájú ìta baba rẹ̀

Gómìnà Mákindé la Adelabu mọ́ iwájú ìta baba rẹ̀

Fẹ́mi Akínṣọlá

Olùdíje fúnpò Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ lórúkọ ẹgbẹ́ òṣèlú Accord Party nínú ìdìbò tó ń lọ lọwọ́, Olóyè Adebayọ Adelabu ti fìdí rẹmi níbùdó ìdìbò rẹ̀.

Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Ẹnjiníà Ṣèyí Mákindé ló là á mọ́lẹ ní gbàdede ìta bàbá rẹ̀ níbẹ̀.

Ibùdó ìdìbò kẹwàá, ní wọ́ọ̀dù kẹsàn-án, lágboolé Oluokun, ní Kudẹti, nijọba ìbílẹ̀ Ila-Oorun Gúúsù Ìbàdàn, nígboro Ìbàdàn tí í ṣe agboolé tí wọ́n bí Adelabu sí náà ló ti máa ń dìbò.

Gẹ́gẹ́ bí aṣojú àjọ elétò ìdìbò nílẹ̀ yìí, INEC ṣe kéde ẹ,ọ̀kàndínláàdọ́rin (69) ìbò ni Mákindé ní. Ṣùgbọ́n èèyàn méjìdínlógójì (38) péré ló dìbò fún Adelabu tó jẹ́ ọmọ agboolé ọ̀hún nígbà tí Sẹ́nẹ́tọ̀ Teslim Fọlarin, olùdíje lórúkọ ẹgbẹ́ òṣèlú APC, tó ṣe ipò kẹta ní ìbò méjìlélógún (22) níbudó ìdìbò náà.

Bí Gómìnà Mákindé ṣe la Adelabu mọ́lẹ̀ nínú ìdìbò Gómìnà ọdún 2019 náà ló tún lù ú mọ́ iwájú ìta bàbá ẹ nínú ìdìbò ọdún 2023 tó wáyé lónìí ọjọ́ kejìdínlógún oṣù kẹta tá a wà yìí.

Bákan náà ni Gómìnà yìí tún fàgbà han gbogbo àwọn tí wọ́n bá a du agbára ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ níbi tí òun fúnra rẹ̀ ti máa ń dìbò níbudó ìdìbò kínní, wọọdu kọkànlá níjọba ìbílẹ̀ Ìlà-Oòrùn Àríwá Ìbàdàn.

Èèyàn mẹ́rìnlèláàádọ́sàn-án (174) ló dìbò fún Gómìnà tí wọ́n tún ń pé ní GSM yìí níbudó ìdìbò náà. Fọlarin, ẹni tó pọwọ́ lé e níbudó ìdìbò ọ̀hún ní ìbò méjìdínlọgbọn (28) péré nígbà tí ìbò Adélabú tó ṣe pò kẹta kò ju ẹyọ márùn-ún péré lọ.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here