Gómìnà Fubara balẹ̀ sí Port Harcourt
Fẹ́mi Akínṣọlá
Gómìnà ìpínlẹ̀ Rivers, Siminalayi Fubara ti balẹ̀ sí ìlú Port Harcourt, olú ìlú ìpínlẹ̀ náà.
Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn tó tẹ̀ wá lọ́wọ́, nǹkan bíi aago méjìlá ọ̀sán kọjá ogún ìṣẹ́jú ni Gómìnà Fubara balẹ̀ sí pápákọ̀ òfurufú Port Harcourt níbi tí àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ ti fi orin àti ijó pàdé rẹ̀.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn obìnrin, ọ̀dọ́, tó fi mọ́ àwọn alátìlẹyìn Fubar ani wọ́n tò sáwọn òpópónà ní Port Harcourt tí wọ́n sì ń kí i káàbọ̀ padà sẹ́nu iṣẹ́.
Níṣe ni àwọn èrò náà ń kọrin, jó káàkiri gbogbo òpópónà ní Port Harcourt lórí bí òpin ṣe ìlú ò fararọ tí ààrẹ kéde níbẹ̀ àti ìpadà sípò ìjọba àwaarawa ìpínlẹ̀ náà.
Ní Ọjọ́bọ̀, ọjọ́ kejìdínlógún, oṣù Kẹsàn-án ni àwọn èèyàn pàápàá àwọn olólùfẹ́ Gómìnà Fubara ti ń retí rẹ̀ ní ìpínlẹ̀ náà àmọ́ tí kò yọjú sí ìpínlẹ̀ ọ̀hún.
Níṣe ni àwọn èrò tó tò sí ilé ìjọba ìpínlẹ̀ Rivers láti gbàlejò Gómìnà Fubara lọ́jọ́rú ṣùgbọ́n tí wọ́n padà sílé nígbà tí wọn kò rí i kó wá sí kó padà sẹ́nu iṣẹ́.
Ẹ ó rántí pé ní Ọjọ́rú, ọjọ́ kẹtàdínlógún ni Ààrẹ Bola Tinubu kéde pé ìlú ò fararọ tí wọ́n kéde ní ìpínlẹ̀ náà ní oṣù mẹ́fà sẹ́yìn ti parí àti pé kí gómìnà, igbákejì rẹ̀ àtàwọn aṣòfin padà sẹ́nu iṣẹ́ wọn.
Nígbà tí àwọn aṣòfin wọlé padà fún ìjòkòó ilé lọ́jọ́bọ̀, Gómìnà Fubara kò yọjú sí ilé ìjọba pẹ̀lú gbogbo bí àwọn èrò ṣe ti tò kalẹ̀ láti gbàlejò rẹ̀.
Ní gbọ̀ngàn tó wà ní ilé ìgbé àwọn aṣòfin náà èyí tó wà ní Aba road, Port Harcourt ni ìjòkòó àwọn aṣòfin ọ̀hún ti wáyé.
Àwọn aṣòfin náà tún sọ fún Gómìnà Fubara láti forúkọ àwọn tó fẹ́ yàn sípò Kọmíṣánnà ṣọwọ́ fún àyẹ̀wò àti ìbuwọ́lù.
Àwọn aṣòfin mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n ló kópa níbi ìjòkòó náà nígbà tí àwọn mẹ́ta – tí ìgbàgbọ́ wà pé wọ́n súnmọ́ gómìnà Fubara – kò yọjú.
Ọjọ́ Ajé, ọjọ́ kejìlélógún ni ìjòkòó míì yóò tún wáyé.
Ẹ̀wẹ̀, gómìnà tẹ́lẹ̀ rí ní ìpínlẹ̀ Rivers, Nyesom Wike, tí òun náà wà lára ọ̀kan lára àwọn tó ṣokùnfà bí ààrẹ ṣe kéde ìlú ò fararọ sọ pé kò pọn dandan kí gómìnà Fubara wọlé padà sẹ́nu iṣẹ́ lọ́jọ́ tí Ààrẹ ní kó padà.