Godswill Akpabio kéde Bamidele, Ashiru, Olalere àtàwọn míì bí adarí ilé aṣòfin àgbà

Godswill Akpabio kéde Bamidele, Ashiru, Olalere àtàwọn míì bí adarí ilé aṣòfin àgbà

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ààrẹ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àgbà, Godswill Akpabio ti kéde orúkọ àwọn adarí ilé tí wọ́n jọ máa darí ilé fún ìgbìmọ̀ ẹlẹ́kẹẹ̀wá yìí.

Opeyemi Bamidele láti ìpínlẹ̀ Ekiti ni adarí ọmọ ilé tó pọ̀ jùlọ nígbà tí wọ́n kéde Dave Umahi láti ìpínlẹ̀ Ebonyi gẹ́gẹ́ bí igbákejì rẹ̀.

Akpabio tún kéde Sẹ́nétọ̀ Ali Ndume gẹ́gẹ́ bí agbọ́pàá ilé tí Sẹ́nétọ̀ Lola Ashiru láti ìpínlẹ̀ Kwara sì jẹ́ igbákejì rẹ̀.

Akpabio ní àwọn sẹ́nétọ̀ ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress, APC ti foríkorí tí àwọn sì ti panupọ̀ láti yan àwọn sẹ́nétọ̀ náà sípò kí àwọn le bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ àwọn ni pẹrẹu.

“Inú mi dùn pé pẹ̀lú ìfẹnukò àwọn sẹ́nétọ̀ ẹgbẹ́ òṣèlú APC, Sẹ́nétọ̀ Opeyemi Bamidele ni yóò máa jẹ́ olórí ọmọ ilé tó pọ̀ jùlọ.”

Bákan náà ló tún kéde Sẹ́nétọ̀ Nwadkwon Davou láti ìpínlẹ̀ Plateau gẹ́gẹ́ bí olórí ọmọ ilé tó kéré jùlọ, tí Kamorudeen Olalere láti ìpínlẹ̀ Osun sì jẹ́ igbákejì rẹ̀.

Darlington Nwokeocha láti ìpínlẹ̀ Abia lẹ́gbẹ́ òṣèlú Labour Party ni agbọ́pàá ọmọ ilé tó kéré jùlọ tí Rufai Hanga láti ìpínlẹ̀ Kano lẹ́gbẹ́ òṣèlú NNPP sì jẹ́ igbákejì rẹ̀.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here