Gbogbo ọjà n’Ìbàdàn wà ní títìpà gbọingbọin saájú ìwúyè
Fẹ́mi Akínṣọlá
Àwọn àgbà bọ̀, wọ́n ní kí á bu ọlá fún ẹni tí ọlá tọ́ sí .Ìbàdàn kíì gbàgbé olóore bọ̀rọ̀.
Bí àwọn ọmọ Ìbàdàn ṣe ń gbaradì fún ayẹyẹ ìfinijoyè Olúbàdàn tuntun ni ọ̀pọ̀ ìgbésẹ̀ ti n lọ létò létò káàkiri ìlú ọ̀hún.
Bẹrẹ lati bi wọn yoo se ti awọn ọna kan pa, eyi ti wọn ti fi to awọn araalu leti nipa awọn ọna miiran ti wọn le lo ti yoo mu irinajo wọn jẹ irọnu.
Bẹẹ naa ni ijọba ipinlẹ Oyo tun si paapa ofurufu Samuel Ladoke Akintola to wa niluu Ibadan, to si ti gba alejo baalu akọkọ lẹyin ti wọn ti pa ninu oṣu kẹta ọdun yii.
Igbesẹ yii lo waye nitori bi ilu Ibadan yoo ṣe ma gba alejo Aarẹ orilẹede Naijiria, Bola Tinubu fun ayẹyẹ ifinijoye Olubadan tuntun.
Baalu yii balẹ ni deede ago mẹsan an kọja isẹju mẹrinla lọjọru, to si pada leyi to mu ọpọ idunu ati ayọ ba araalu.
Aarẹ Bola Ahmed Tinubu ni igbagbọ wa pe yoo balẹ si ilu Ibadan ni Ọjọ Ẹti fun ayẹyẹ Olubadan tuntun, Oba Rashidi Adewolu Ladoja.
Bakan naa, Babaloja gbogbo ipinlẹ Oyo, Asiwaju Yekeen Abass ti paṣẹ pe ki gbogbo ọja pata niluu ibadan di titi pa ṣaaju eto ifinijoye Olubadan.
Ifinijoye yii ni yoo waye ni ọjọ Kẹrindinlọgbọn oṣu kẹsan an ọdun 2025 ni gbọngan Mapo niluu Ibadan, to jẹ olu ilu fun ipinlẹ Oyo.
Ikede yii lo wa ninu atẹjade ti Babalọja fi sita fun awọn akọroyin lati fi ki Olubadan tuntun, Oba Rasidi Adewolu Ladoja ku orire ifinijoye gẹgẹ bii Olubadan kẹrinlelogoji
Babalọja rọ gbogbo awọn ọlọja ni ijọba ibilẹ mọkanla to wa ni ilu Ibadan pe ki wọn ti ọja wọn pa lati bu ọla fun ori ade tuntun.