Gbèse súyọ,màálù tó súnmọ àádọ́ta jẹ́ májèlé n’llọrin,wọ́n kú gífà
Ọ̀rẹ Òtítọ́jù
À fi kí Ẹlẹ́dàá ó fòfò rẹ̀mí ni látàrí àjálù tó bẹ́lu àwọn òntàjà wọ̀nyí.
À fi bíígbà tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ lọ̀rọ̀ rí fún àwọn òntàjà kan tí wọ́n n ta màálù nínú ọjà Mandate, Adewọle, nílùú Ilọrin, ti i ṣe olú ìlú ìpínlẹ̀ Kwara, wà báyìí, pẹ̀lú bí màálù wọn tó lé ní ogójí ṣe kú lójijì látàrí májèlé tí wọ́n jẹ lọ́jọ́ Àbámẹ́ta, ogúnjọ́, oṣù Kẹrin, ọdún 2024 yìí.
Oun ti a gbọ ni pe awọn ontaja ọhun ni wọn lọọ fi awọn maaluu wọn jẹko lati inu ọja Mandate, lọ si inu ọgba ileewe College of Arabic and Legal Studies, to wa ni agbegbe naa, ṣugbọn nigba ti wọn n dari pada bọ wale nirọlẹ ni awọn maaluu ọhun bẹrẹ si i wo lulẹ, ti wọn si n ku eyi to mu ki maaluu to le ni ogoji ku loju-ẹṣẹ, ti wọn si n sọ ọbẹ si wọn lọrun.
Ọkan lara awọn to n taja ọhun ti orukọ rẹ n jẹ Olugbọn, to ba oniroyin ṣọrọ ṣalaye pe lasiko tawọn maaluu naa n dari bọ lati ibi ti wọn ti lọọ jẹ koriko ni wọn n ṣubu lulẹ latari pe wọn jẹ majele mọ ounjẹ ti wọn jẹ, o ni ọkẹ aimọye miliọnu lawọn ti padanu bayii ṣibi iṣẹlẹ buruku naa.
Olugbọn, ti waa rawọ ẹbẹ sijọba Kwara atawọn ẹlẹyinju aanu pe ki wọn ran awọn lọwọ lori adanu naa, nitori pe gbese nla lo wọle tọ awọn lasiko ti eto ọrọ-aje dẹnu kọlẹ, ti gbogbo nnkan ko si jọra wọn tẹlẹ, aforiti lawọn n ṣe.
Babalọja inu ọja naa fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, o ni iṣẹlẹ ibanujẹ niṣẹlẹ naa jẹ fun gbogbo awọn to n ta maaluu ninu ọja, wọn waa rọ Gomina ipinlẹ Kwara, Abdulraman Abdulrasaq, ko dide iranwọ fun awọn tọrọ kan.