Gbajúmọ̀ oníṣòwò ẹja, Fish Magnet, bọ́ sọ̀wọ̀ ajínigbé nílé rẹ̀,òkú rẹ̀ ní wọn rí lẹ́yìn sísan owó ìdáǹdè

Gbajúmọ̀ oníṣòwò ẹja, Fish Magnet, bọ́ sọ̀wọ̀ ajínigbé nílé rẹ̀,òkú rẹ̀ ní wọn rí lẹ́yìn sísan owó ìdáǹdè

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Anambra ti bẹ̀rẹ̀ sí ní tọpinpin àwọn agbébọn tó ji ọ̀dọ́kùnrin kan, Ifesinachi Onyekere, gbé nílé rẹ̀ kí wọ́n tó gbẹ̀mí rẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n gba owó ìtú sílẹ̀ rẹ̀ tán.

Oloogbe naa, ti ọpọ mọ si “Fish Magnet” ni a gbọ pe o jẹ ọmọ oloṣelu kan lagbegbe naa ṣaaju iku rẹ.

Ọjọ Abamẹta to kọja ni awọn agbebọn naa ya bo ile rẹ to wa ni Okpuno, ni ijọba ibilẹ guusu Akwa.
A gbọ pe ibẹrubojo ba ọkan awọn eeyan agbegbe ti ọdọkunrin naa n gbe latari bi awọn agbebọn naa ṣe n yinbọn soke nigba ti wọn wa gbe nile rẹ.

Iroyin ni wọn kọkọ yinbọn fun ni ẹsẹ rẹ ki wọn to gbe lọ.
orukọ ara rẹ lede sọ pe “nnkan bii aago mẹwaa abọ alẹ ni wọn ya bo ile naa.

Wọn gbe ọkunrin naa lọ ninu ọkọ Toyota Corola rẹ lẹyin ti wọn yinbọn lu u ni ẹṣẹ tan.

“Inu igbo to wa loju ọna Nawfia ni wọn gba salọ, bi wọn ṣe n lọ ni wọn n yinbọn soke, eyii to da ibẹru sọkan ọpọ eeyan agbegbe ọhun.”

O fi kun pe awọn ọdẹ adugbo atawọn ọlọpaa bẹrẹ iṣẹ lẹyin naa lati ṣawari rẹ amọ oku rẹ ni wọn ri lẹyin naa.

O ni “ọjọ mẹta gbako lo fi wa lakata wọn titi ti wọn fi gba owo itusilẹ rẹ, amọ kaka ki wọn tu silẹ lẹyin ti wọn gba owo naa tan, oku rẹ ni a ri lẹba ọna laarọ oni.”

Ọkunrin naa juwe oloogbe ọhun gẹgẹ bii ọdọ to mura siṣẹ rẹ, ti ko si ṣe ọlẹ.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa, SP Tochukwu Ikenga, ti fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ.

O ni kọmiṣọna ọlọpaa ti da awọn ọtẹlẹmuyẹ si igboro lati ṣawari gbogbo awọn to lọwọ ninu iku ọkunrin naa to jẹ oludasilẹ ileeṣẹ Fish Magnet Outlet.

Ọlọpaa ni “aṣẹ yii lo waye lẹyin ti olọpaa ṣawari ọkọ ayẹkẹlẹ Toyota Corolla rẹ alawọ aro loju ọna Ukwulu/Igbariam.

“Iwadii wa fi han pe awọn kọlọrọsi naa ti kọkọ n tọpinpin rẹ ki wọn to kọlu u nibi ti wọn ti yinbọ lu ẹsẹ rẹ ki wọn to gbe lọ.

“Lẹyin naa ni awọn eeyan ṣawari oku rẹ eyii to ti da ibẹrubojo sọkan awọn eeyan agbegbe Akwa bayii.”

Alukoro ọhun ṣeleri pe iwadii kikun yoo waye, gbogbo awọn to lọwọ ninu iwa laabi naa yoo si foju wina ofin.