Fresh FM rédíò Ayefele padà sórí afẹ́fẹ́ lẹ́yìn ìjàmbá iná

Fresh FM rédíò Ayefele padà sórí afẹ́fẹ́ lẹ́yìn ìjàmbá iná

Fẹ́mi Akínṣọlá
Yoruba bọ̀ wọ́n ní bí a ò kú, ìṣe sì kù ,bayii gan an lọ̀rọ̀ rí pẹ̀lú Fresh FM iléeṣẹ́ rédíò gbajúgbajà Olórin ẹ̀mí, Yinka Ayefele, tó tì padà sórí afẹ́fẹ́ báyìí lẹ́yìn ìjàmbá iná tó sẹlẹ̀ níbẹ̀.

Ina ọhun to ṣẹyọ níléeṣẹ́ redio naa ni nnkan bii ago meje abọ alẹ ana ọjọ Ẹtì jo irinṣẹ igbohunsafẹfẹ at’awọn ọpọlọpọ dukia mii rau rau níléeṣẹ́ redio Fresh FM.

Amọ, agbẹnusọ fun Yinka Ayefele àti Fresh FM ti ṣalaye loju opo Instagram ileeṣẹ redio naa wi pe awọn ti bẹrẹ igbohunsafẹfẹ pada.
“Inu wa dun lati kéde wí pé ileeṣẹ redio Fresh FM ti pada sori afẹfẹ lẹyìn ipenija ijamba ina to sẹlẹ lalẹ ana ọjọ Ẹti.

A n fi asiko yii dupẹ lọwọ awọn oṣiṣẹ wa, awọn oṣiṣẹ iṣẹlẹ pajawiri to fi mọ awọn ololufẹ Fresh FM fun atilẹyin gbogbo yin.