Folajimi Oyekunle ẹgbẹ́ PDP wọlé àtúndì ìbò Ibadan North
Fẹ́mi Akínṣọlá
Àjọ elétò ìdìbò INEC ti kéde Họnọrébù Folajimi Oyekunle Olùdíje ẹgbẹ́ òṣèlú PDP gẹ́gẹ́ bíi ẹni tó jáwé olúborí nínú àtùndì ìbò aṣojú-ṣòfin nílùú Àbújá fún ẹkùn àríwá Ìbàdàn.
Ọjọgbọn Abiodun Oluwadare Fasiti UI, to jẹ ọga INEC fun eto idibo naa lo ṣe ikede yii nibi ti wọn ti ko esi ibo jọ nile ẹkọ girama Ikolaba niluu Ibadan lanaa ọjọ Abamẹta ọjọ kẹrindinlogun oṣu Kẹjọ yii.
Gẹgẹ bii esi ibo ti INEC kede, Họnọrebu Oyekunle ẹgbẹ PDP ri ibo 18,404, to si la Họnọrebu Adewale Olatunji ẹgbẹ oṣelu APC to ni ibo 8,312 mọlẹ.
Ni bayii, Họnọrebu Oyekunle ni yoo rọpo oloogbe Họnọrebu Musiliu Olaide Akinremi (Jagaban) to ku lọdun 2024 eyi to ṣokunfa atundi ibo to waye.
Ọpọ eeyan lo ti n dunnu si bi Họnọrebu Oyekunle ṣe bori ninu atundi ibo naa, tori igba akọkọ ree ti ẹgbẹ oṣelu PDP yoo wọle ibo aṣoju-ṣofin l’Abuja lẹkun ariwa Ibadan lati ọdun 2011.
Ọgọọrọ awọn ọmọ ẹgbẹ PDP lo n fo fayọ lẹyin ti INEC kede Họnọrebu Oyekunle gẹgẹ bi oludije to jawe olubori ninu eto idibo ọhun.
Wọn ni eyi fi han pe ẹgbẹ oṣelu PDP n rinlẹ si i nipinlẹ Oyo.