Fẹ́mi Akínṣọlá
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn eré ìtàgé àti sinimá làwọn àgbà òṣèré ní ilẹ Yorùbá ti gbé jáde eléyìí tó ti mi orílè-èdè Nàìjíríà àti òkè òkun tì tì tì. Ṣaaju asiko yii, itan ati agbekalẹ ere Yoruba maa n mu ọpọlọpọ lọkan to bẹẹ gẹ ti awọn ti kii ṣe ọmọ Yoruba gan maa n fi oju sọna lati wo awọn sinima yii.
Bẹẹ, awọn ti ko si gbọ ede Yoruba pẹlu nigba naa, maa n joko ti awọn eeyan to ba gbọ lati maa tu ohun ti wọn ba sọ.
Idi ni pe igbesẹ ṣisẹ-n-tẹle awọn ere sinima naa, maa n fa eeyan to ba n wo o lọkan, yala o gbọ ede Yoruba ti wọn n sọ ni tabi ko gbọ. Awon fiimu wonyi wa niwaju awon to je karaye mo pe ere tiata ni ile Yoruba ko see fowo ro seyin:
OGBORI ELEMOSO
Ko si aniani bi eeyan ba sọ pe sinima ‘Ogbori Ẹlẹmọṣọ’ wa lara awọn sinima to jade ni ilẹ Yoruba to si jẹ manigbagbe. Sinima ti ọwọja rẹ tan kalẹ kọja orilẹede Naijiria ni ti ọpọ ẹya ati ede si wo o.
Iṣe ati itan ere naa pẹlu awọn oṣere to ṣe ni wọn dun un wo.Itan iṣẹdalẹ ilu Ogbomọṣọ ni ‘Ogbori Ẹlẹṣọ’.
Lalude ko ipa takuntakun ninu ere naa , ti Lere Paimọ si ko ipa Ṣọun Ogunlọla nibẹ.
TI OLUWA NILE
Ere kan ti ọpọ ọmọ Yoruba, paapaa julọ awọn onworan sinima Yoruba, fẹran pupọ ni sinima ‘Ti Oluwa nilẹ’.
Ninu sinima yii ni Alhaji Kareem Adepọju ti ọpọ mọ si Baba Wande ti di ilu mọọka.
Sinima to kọ ni lẹkọọ, to si tun panilẹrin ni.
Ti Oluwa nilẹ da lori pataki ti Yoruba so mọ awọn dukia ilu, paapaa ilẹ Oriṣa.
Ohun to gbe soke ni bi Yoruba ṣe maa n bọwọ fawọn ohun iṣẹdalẹ rẹ pẹlupẹlu idukoko aṣa ọlaju.
Awọn eeyan kan fẹ ra ilẹ fi ṣe owo nla ni wọn ba kan si oloye ilu naa kan, iyẹn Oloye Ọtun (Baba Wande)
Wọn gbe owo gọbọi fun lẹyin o rẹyin gbogbo awọn to lọwọ si tita ilẹ naa loriṣa ilu naa pa.
Adapọ awada laarin ẹkọ ti wọn fẹ fi sinima naa gbe jade tun jẹ ki ọpọlọpọ onworan o tun gbadun sinima naa pẹlu awọn eekan alawada bii Kayọde Ọlaiya (Adẹrupọkọ)
Tunde Kelani lo dari ere naa naa lọdun 1993, Kareem Adepoju lo kọ ọ.
Awọn agba oṣere bii Dele Odule, Lekan Oladapo, Yemi Shodimu, Yetunde Ogunsola, Oyin Adejobi, Gbolagbade Akinpelu, Jide Oyegunle ati Akin Sofoluwe naa kopa ninu ere naa.
O LE KU
Ọkan lara awọn iwe akagbadun ti Ọjọgbọn Akinwunmi Iṣhọla kọ ni ọdun 1974 ni ‘O Le Ku’.
Fiimu yii ni eekan onisinima, Alagba Tunde Kelani sọ di sinima ni ọdun 1997.
Itan ere ifẹ laarin ololufẹ Aṣakẹ, Lọla ati Ṣade ti wọn fẹ fẹ Ajani ni nnkan bii aadọta ọdun

sẹyin ni iwe ati sinima yii.
Gbogbo ohun elo ti wọn si lo nibẹ lo ṣe afihan eyi.
Sinima yii lo si ṣe agbende iro ati buba ti ko ju orokun lọ tawọn eeyan n lo ni aye igbaun pada sagbo faari eyi ti a wa n pe ni iro ati buba o le ku.
Ajani jẹ akẹkọ ipele aṣekagba ni fasiti to n wa afẹsọna nitori ipe iya rẹ to n fẹ ko ṣe igbeyawo ni kiakia.
Sinima yii rinlẹ lasiko to jade nigba naa.
KOTO ORUN
Ọkan lara awọn ere to gbilẹ ni nnkan bii ọgbọn ọdun sẹyin ni ere yii.
Oloogbe Yekini Ajilẹyẹ lo ṣe.
Nigba naa, awọn ere to ṣe afihan igbagbọ Yoruba ninu aye akamara ni oloogbe Ajilẹyẹ maa n ṣe nigba naa.
Ija laarin awọn awọn ẹlẹyẹ funfun ati dudu ni sinima naa da le lori.
Awọn agba oṣere bii Oloogbe Ajilẹyẹ, Oyiboyi, Kọledowo, oloogbe Oriṣabunmi, Abija ati bẹẹbẹ lọ lo wa ninu sinima yii.
YEMI MY LOVER
Ọkan lara awọn ere sinima to milẹ nigba to jade ree ni sinima ‘Yemi My Lover’.
Ere ifẹ ni Alagba Yẹmi Ayebọ maa n saba n ṣe nigba naa pẹlu awọn orin ifẹ ninu rẹ.
Lẹyin ipapoda Ade Love, ko fi bẹẹ si awọn sinima ifẹ to ni alafibọ orin ninu mọ ki Yẹmi Ayebọ to de pẹlu sinima ‘Yẹmi my Lover’.
Sinima naa da lori ọrọ ifẹ to wa laarin omidan Moji ati Yẹmi ṣugbọn ti o ba inira diẹ pade.
Lọdun 1990 ni ere naa jade, awọn osere bii Abija, Yẹmi lukuluku, Thompson, Alabi yellow ati bẹẹbẹẹ lọ lo kopa ninu sinima naa.
ERAN IYA OSOGBO
Ere miran, ‘Ẹran Iya Osogbo’, niyi to tun gbajumọ lọpọ ọdun sẹyin. Alhaji Yẹkini Ajilẹyẹ lo gbe sinima naa jade nigba naa.
Itan ewurẹ abami kan to n hu iwa buruku ni sinima yii da le lori.
Awọn agbaagba oṣere bii Grace Oyin-Adejọbi (Iya Osogbo), Kọledowo, ati bẹẹbẹlọ si lo kpa ninu sinima naa.
OWO BLOW
Ọkan lara awọn gbajumọ ere sinima to waye laarin ogun ọdun si ọgbọn ọdun sẹyin ni sinima ‘Owo Blow’ jẹ.
Ọpọ onwoye sinima Yoruba lo si n sọ pe ere yii gan lo sọ Taiwo Hassan (Ogogo) ati Yinka Quadri (Kura) di gbajugbaja.
Sinima naa da lori ọdọkunrin kan to di janduku ati ọlọsha lẹyin ti wahala awọn ẹbi rẹ tii sita.
Awọn agbofinro ran baba rẹ lọ sẹwọn, ileewe si lee jade nitori aile san owo ileewe.
Wọle gbiyanju ohun gbogbo to lee ṣe lati tọju iya rẹ atawọn aburo rẹ ṣugbọn ko bọ si.
Wọn ko o mọ “roga” ti ko si fẹ pada lọ ba iya rẹ mọ nitori ojuti.
Awọn eekan osere to kopa ninu rẹ ni Racheal Oniga, Bayo Bankole, Adebayọ Salami (Ọga Bello), Adewale Ẹlẹṣọ, Kayọde Odumoṣu, Binta Ayọ Msgaji, Sam Loco Efe, Bimbọ Akintọla, Ọmọọba Leke Ajao.

LARINLOODU
Ere awada ni ‘Larinlọọdu’ jẹ.
Awọn eekan alawada igba naa, Babatunde Omidina (Baba Suwe) ati aya rẹ oloogbe Monsurat Omidina (Mọladun) ni aayo ninu sinima yii.
Gbajugbaja agbe sinima sita to kopa ninu ere naa ni, Shan George, Jide Kosọkọ, Yọmi King (Ọpẹbẹ), Yẹmi Ẹlẹshọ, Dele Odule.
Muka Ray, Rẹmi Surutu, Doris Simeon, oloogbe Henrietta Kosokọ, oloogbe Alaaran, oloogbe Yọmi Ogunmọla, Gbenga Adewusi naa ba wọn lọwọ si sinima naa nigba naa.
Itan rẹ da lori Baba onile kan (Baba suwe).
ABELA PUPA
Ara awọn sinima ti alagba Ọlaiya gbe sita ni ‘Abela Pupa’.
Oloogbe Wolii Ajidara ko ipa manigbagbe ninu sinima yii.
Sinima naa da lori fifi ipa wa owo pẹlu awọn alafibọ awada ninu rẹ.
Awọn eekan oṣere bii Femi Branch, Bimbọ Oshin, Ajidara, Ọlaiya ati bẹẹbẹẹ lọ lo kopa ninu sinima naa.
SAWORO IDE
Ara awọn sinima ti Tunde Kelani gbe jade ni ‘Saworo Idẹ’.
Itan to yannana ipo eto oṣelu lorilẹede Naijiria nigba naa ni.
Lasiko ti orilẹede Naijiria wa labẹ iṣejọba ologun to si n gbaradi fun ijọba alagbada ni wọn gbe sinima naa sita.
Awọn eekan oṣere bii Kọla Oyewọ, Lere Paimọ, Bukky Wright, Kunle Bamtẹfa, Kọla Ọlaiya (Adẹrupọkọ), oloogbe Bayọ Faleti, Ọjọgbọn Akinwunmi Ishọla lo wa ninu sinima naa.
Ere yii lo gbe Kunle Afọlayan ati Kabirat Kafidipẹ jade faye ri.
Lara awon fiimu miran to rinle lawon asiko ti a n so yii ni OMO ORUKAN, IRU ESIN ati OLOLADE MR MONEY.
A o tun ranti awon kan bii ORI, MADAM DEAREST, KKK (Ko Dun, Ko Po, Ko Pe ati OWO EJE.