Ètò ìgbadé Ọba Rashidi Ládọjà gẹ́gẹ́ bí Olúbàdàn tuntun
Fẹ́mi Akínṣọlá
Àwọn àgbà bọ̀ wọ́n ní inú ẹni kìí dùn, kí á pà á mọ́ra, ló mú kí ìgbìmọ̀ tó ń mójútó fífi Olúbàdàn Kẹrìnlélógójì , Ọba Rasidi Adewolu Ladoja, jẹ́, ṣe kéde bí wọ́n yóò ṣe fi ọ̀sẹ̀ kan gbáko ṣètò ayẹyẹ ìgbadé náà nílùú Ìbàdàn.
Ikede igbade naa waye lẹyin ipade igbimọ ipo Olubadan ti wọn ṣe lọjọ Aje, ọjọ kin-in-ni, oṣu Kẹsan-an ọdun 2025, eyi ti Alaga igbimọ naa, Oloye Bayo Oyero, lewaju rẹ.
Bakan naa, Kọmiṣanna eto iroyin nipinlẹ Oyo, Ọmọọba Dotun Oyelade, ṣalaye pe eto igbade naa yoo bẹrẹ lọjọ Aje, ọjọ kejilelogun, oṣu Kẹsan-an ọdun 2025.
O ni eto ọlọkan-o-jọkan to ni i ṣe pẹlu aṣa, Iṣẹṣe ati ẹ̀kọ́ ni yoo maa waye lati Mọnde naa titi di ọjọ Ẹti, ọjọ kẹrindinlọgbọn oṣu Kẹsan-an ti gbogbo rẹ yoo wa sopin ni gbọngan Mapo, Ibadan.
Isin apapọ nilana ẹsin Kristẹni (Interdenominational service) ni wọn yoo fi ṣide ayẹyẹ igbade naa ni Mọnde, ọjọ kejilelogun, oṣu Kẹsan-an.
Aafin Olubadan to wa ni Oke Aremo, niluu Ibadan ni yoo ti waye. Ẹgbẹ CCII lo ṣagbatẹru rẹ bi ikede ṣe ṣalaye.
• Ọjọ Aṣa (Cultural Day) lo kan, iyẹn lọjọ Iṣẹgun, ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kẹsan-an, eyi ti wọn gbe kalẹ pẹlu ajọṣepọ ileeṣẹ ijọba to n ri si Aṣa ati Irinajo afẹ nipinlẹ Oyo.
Lẹyin eyi ni wọn yoo ṣe idanilẹkọọ lori igbade Olubadan. Agba onpitan, Ọjọgbọn Toyin Falola, ni yoo ṣe idanilẹkọọ ọhun.
Ọjọbọ ni wọn ya sọtọ fun isin agbayanu, eyi ti yoo waye ni Civic Centre, Idi Ape, Ibadan.
Ọjọ Ẹti, ọjọ kẹrindinlọgbọn oṣu Kẹsan-an gan-an ni Olubadan tuntun yoo gba ade ni Gbọngan Mapo bi wọn ṣe la a kalẹ.
Gẹgẹ bi Kọmiṣanna eto iroyin nipinlẹ Oyo ṣe wi nipa awọn aṣoju igbimọ Olubadan to wa nibi ipade ti wọn ti la eto yii kalẹ, o ni awọn alẹnulọrọ nipinlẹ naa ni.
Lara wọn ni: Awọn aṣoju Olubadan, Aṣipa Olubadan ti wọn yan sipo, Oba Hamidu Ajibade; Oloye Nureni Adisa ati Oloye Adeola Oloko to jẹ Akọwe iroyin fun Olubadan.
Awọn mi-in ni: Kọmiṣanna Aṣa ati Irinajo afẹ, ati ti eto awọn obinrin.
Awọn alaga ijọba ibilẹ Egbeda ati Guusu-Ila-Oorun Ibadan, awọn ọmọ ile igbimọ aṣofin lati Guusu-Ila-Oorun Ibadan ati bẹẹ bẹẹ lọ.