Ètò ìdìbò láti yan ààrẹ Cameroon gbérasọ

Ètò ìdìbò láti yan ààrẹ Cameroon gbérasọ

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ètò ìdìbò láti yan ààrẹ ní orílẹ̀ èdè Cameroon ti gbérasọ, táwọn aráàlú sì ti bẹ̀rẹ̀ ìbò dídì.

Èèyàn tó lé ní mílíọ̀nù mẹ́jọ ní ìrètí wà pé wọ́n yóò kópa níbi ètò ìdìbò náà láti yan ààrẹ tó wù wọ́n.

Níṣe ni àwọn olùdìbò ti tò kalẹ̀ ibùdó ìdìbò Bilingual Primary School Bastos ní Yaoundé, olú ìlú orílẹ̀ èdè Cameroon, níbi tí ààrẹ Paul Biya àtàwọn ẹbí rẹ̀ yóò ti dìbò.

Ọ̀dọ́ kan, Gabriel, tó ń dìbò fún ìgbà àkọ́kọ́ sọ pé inú òun ń dùn lórí ètò ìdìbò náà nítorí òun ń kópa láti yan ààrẹ orílẹ̀ èdè àwọn.

“À ń fẹ́ ààrẹ tó máa súnmọ́ wa, ààrẹ tó máa súnmọ́ àwọn aráàlú,” ẹni ọdún mẹ́rìnlélógún náà sọ fún akọ̀ròyìn.

Ó ní ó wu òun láti ri pé gbogbo èèyàn kópa wọn lójúnà àti ri pé ètò ìdìbò náà lọ ní ìrọwọ́rọsẹ̀ tó fi mọ́ àjọ tó ń rí sí ètò ìdìbò, Elecam.
Ní àwọn ẹkùn tí wọ́n ti ń sọ èdè Gẹ̀ẹ́sì, àwọn tí wọ́n ń gbìyànjú láti yapa kúrò ní orílẹ̀ èdè náà ti kéde òfin kónílé gbélé ní agbègbè náà ṣùgbọ́n àwọn olùdìbò kan ti wà ní ibùdó ìdìbò.

Àwọn tó ń gbìyànjú láti yapa náà fòfin dé àwọn aráàlú láti má kópa níbi ètò ìdìbò náà.

Àwọn olùdíje ló ń díje du ipò ààrẹ Cameroon tó fi mọ́ ààrẹ Paul Biya tó ń díje fún ìgbà kẹjọ.

Ó ti lé ní ogójì ọdún tí Ààrẹ Paul Biya ti wà nípò ààrẹ Cameroon.

Láti bíi ọ̀sẹ̀ méjì sẹ́yìn ni àwọn olùdíje ti ṣe ìrìnàjò káàkiri orílẹ̀ èdè náà láti polongo, tí wọ́n sì ń sọ fún aráàlú láti dìbò fún wọn.

Níṣe ni àwọn èèyàn kan ti ń kọminú lórí bí Biya kò ṣe yọjú sí ọ̀pọ̀ ibi ìpolongo ètò ìbò.

Ẹ̀ẹ̀kan péré ló yọjú sí ibi ìpolongo ìbò ní ẹkùn àríwá orílẹ̀ èdè náà lẹ́yìn tó lo ọjọ́ mẹ́wàá ní ilẹ̀ Yúróòpù.
Biya, ẹni ọdún méjìléláàádọ́rùn-ún, kò ì tíì pàdánù ètò ìdìbò kankan rí, táwọn èèyàn sì gbàgbọ́ pé òun náà ló máa borí ètò ìdìbò yìí.

Tí ó bá tún wọlé ìbò yìí tó sì parí sáà rẹ̀, ó túmọ̀ sí pé ó máa ṣe ìjọba fún àádọ́ta ọdún, èyí tó túmọ̀ sí pé ó máa ku ọdún kan tó máa pe ọgọ́rùn-ún ọdún láyé.