Ènìyàn mé̩rin jé̩pè O̩ló̩run níbi ìwúyè ní Alimo̩s̩o̩
Ìròyìn Òwúrò̩
Ki Eledua ma je̩ a ki a si ode lo̩. E̩ni ori yo̩, o di ile ni nigba ti ise̩le̩ nla se̩le̩ nibi iwuye ni ilu Alimo̩s̩o̩ to wa ni ipinle̩ Eko.
Opopona Anjo̩rin ni iwuye ti n waye nigba ti o̩ko̩ Tipa to ko ye̩pe̩ de, awo̩n to wa nibi inawo n gbiyanju lati fun o̩ko̩ oniye̩pe̩ naa lo̩na lati ko̩ja.
Awo̩n to wa ni agbegbe ibi ti wo̩n ta tanpoli si dide lati f’o̩wo̩ kun gbigbe kanopi naa pe̩lu o̩mo̩ onimo̩to ye̩pe̩ naa.
Awo̩n eniyan yii ko mo̩ pe waya ina kan ti ja sile̩, afi igba ti wo̩n gbe irin kanopi le waya naa ni awo̩n ti o̩wo̩ wo̩n kan e̩se̩ kanopi be̩re̩ si ni subu.
Bi ere bi awada, o̩ro̩ naa di tooto̩, awo̩n to subu ko le dide, ki o to di wi pe awo̩n kan taju kan ri waya ina.
Awo̩n to mo̩ nipa is̩e̩ ina sare yo̩ ina kuro lara opo, wo̩n si sare ko awo̩n to subu lo̩ si ile iwosan.
Aisan lo see wo, a ko ri ti o̩lo̩jo̩ se. Awo̩n alejo me̩ta pe̩lu o̩mo̩ onimo̩to ye̩pe̩ ko ye is̩e̩le̩ buruku naa.









