Èmi ò lè gba obìnrin lákọ̀wé mọ́ – Pastor Adeboye

Èmi ò lè gba obìnrin lákọ̀wé mọ́ – Pastor Adeboye
Yínká Àlàbí
Olori ijọ Redeem, Pastor Enoch Adeboye, ṣalaye idi ti wọn kò fi tún gba akọwe obinrin mọ́. Wọn ní awọn ṣe bẹ́ẹ̀ láti yà ara sọ́tọ̀ kí ohunkóhun má bà a di isẹ Oluwa lọwọ.
Alaye lori itan “Jonah Must Go” ní Holy Ghost Congress 2025” waye.
Baba rántí bí wọn ti ní akọwe obinrin ní Ebute Mẹta ṣùgbọ́n ọkan baba ko muu lọ si Ipagọ ti Lagos/Ibadan nitori ibẹru Olorun ati pe “ẹlẹran ara ni oluso aguntan naa”.
Baba Adeboye tún salaye bí wọn ṣe fún àwọn wòlíì RCCG méjì ni awọn imọran to gbopan ju awọ Erin lọ. Ẹni akọkọ salaye bi irin ajo aye rẹ se fẹ daru, baba si salaye fun un ki o lọ da akowe rẹ duro ki o ba le tẹ siwaju nibi isẹ Oluwa.
Ẹnikeji ti ko tete gba imọran, isẹ to gbe lọwọ daru.
Lẹyin ọpọlọpọ apẹẹrẹ awọn ise ti awọn akọwe obinrin ti daru mọ awọn ojisẹ Olorun lọwọ, ni ilẹ yii ati ni oke okun. Pastor Adeboye parí pelu pé kí Kirisitẹni gé gbogbo ìbáṣepọ̀ tó lè ba isẹ jẹ mọ wọn lọwọ, ki wọn si pọkan pọ si iṣẹ Ọlọ́run.
Pastor Adeboye ni awọn mọ ara awọn ki awọn to gba isẹ Ọlọrun. Iṣẹ yii ni ọfiisi le mu ki awọn di aago meji si mẹta oru pẹlu obinrin, eyi to lewu fun ẹlẹran ara.
Ojisẹ yii fi apẹẹrẹ Jonah bo se wa ninu iwe mimọ kọ awọn ọmọ ijọ lẹkọọ ninu ipagọ to n lọ lọwọ bayii.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here