Èmi kò tó Fathia Balogun fé̩ – To̩pe̩ Adebayo̩ Salami
Mary Fágbohùn
Oṣere ati oludari ere Nollywood, Tope Adebayo, ti a mọ si Waheed ninu fiimu TV ti o gbajumọ, “Jenifa’s Diary” ti tako awọn aheso ti o ti pẹ nipa ibasepo ifẹ pẹlu agba oṣere, Faithia Balogun.
Ninu ifọrọwero̩ kan to ṣe laipe yii lori ikanni YouTube Baba Ibe TV, Adebayọ jẹwọ pe oun ni ibatan timọtimọ pẹlu Balogun, ẹni ti o dagba ju oun lọ, ṣugbọn o sọ pe ko si ifẹnumọ kankan laarin wọn.
O fi ibanujẹ han lori aheso naa, o ṣapejuwe rẹ bi eke ati eyi ti o ṣeeṣe pe ki Ibasepo timotimo won se okunfa.
Adebayo nigba to n soro lori iroyin to dun un ju ninu ile-ise naa, o ni, “Iro kan to dun mi lokan ni nigba ti awon eeyan fi esun kan eniyan bii temi pe mo n ba Aunty Faithia se. Se o mu opolo wa?
“Otitọ ni wi pe, iwọ lo fi esun yii kan mi ati pe ẹnu rẹ ni. Bi emi ati Aunty Fathia se sunmo ara wa pekipeki to, ko si ẹnikan ti o le mọ bi asopọ wa se lagbara to.
“Ṣugbọn, maa fi asiri kan silẹ fun ọ lonii, Fathia ati emi yoo tẹsiwaju lati wa nitosi ara wa nitori pe o jẹ oluranlọwọ mi.”
O salaye siwaju sii pe Balogun ti wa ni igun re nigba gbogbo, o si se atileyin fun ala re lati di oludari, paapaa lasiko ti baba oun, Salami Adebayo, ti a mo si Oga Bello n ṣiyemeji agbara oun lati se iyipada naa.
“Mo sọ fún bàbá mi pé mo fẹ́ di olùdarí, àmọ́ ó rẹ́rìn-ín, ó sọ fún mi pé kì í ṣe iṣẹ́ tó rọrùn, ìyẹn sì fẹ́rẹ̀ẹ́ mú mi rẹ̀wẹ̀sì.
“Aunty Faithia wa nibẹ, nitori naa o kọju si baba mi, o sọ pe emi ni maa dari awọn iṣẹ fiimu re marun-un to n bọ.
“Mo n sọ fun ọ pelu ariwo ati ni kedere pe lati isẹ oludari akoko yii pẹlu iṣẹ akanṣe rẹ ni gbogbo agbaye ti gbagbọ ninu agbara mi, ati pe o ṣe ifilọlẹ mi bi oludari,” ni o salaye.
Adebayo sọ pe ẹnikẹni ti o ba duro ti o̩ ni akoko iṣoro ati aidaniloju ni ko yẹ ki o gbagbe. O fi han pe diẹ ninu awọn iṣẹ akanṣe Faithia Balogun ti o lowo si ni o jẹ aṣeyọri nla.
“O kan dun mi pe awọn eniyan gbagbọ pe nitori pe a sun mọ ara wa, dajudaju o tumo si pe a gbọdọ ni ibaṣepọ.
“E jọ̀wọ́, mo fẹ́ bẹ àwọn olùgbọ́ wa pé kí wọ́n mú èrò náà kúrò pé bí àwọn ako̩ ati abo ba ti sun mo̩ ara wo̩n, pé wọ́n ń fẹ́ra wọn ni,” o ma se o.