Ẹ̀kún rẹ́rẹ́ ìròyìn tó ṣàfihàn Abdulrahman Bello ati awọn mẹrin mii saájú kí adájọ́ tó ní kí *wọ́n* yẹgi fún un

Ẹ̀kún rẹ́rẹ́ ìròyìn tó ṣàfihàn Abdulrahman Bello ati awọn mẹrin mii saájú kí adájọ́ tó ní kí *wọ́n*
yẹgi fún un

̣Fẹ́mi Akínṣọlá

Ọgbà ilé ẹjọ́ gíga ipinlẹ̀ kwara kún fọ́fọ́ lónìí, ti ẹsẹ̀ kò sì gba èrò tó péjú sílé ẹjọ́ ọ̀hún.

Gbogbo wọn si lo fẹ fi eti wọn gbọ, ki wọn si fi oju wọn ri bi asekagba idajọ lori ẹsun ipaniyan ati ifipabanilopọ, ti wọn fi kan Abdulrahman Bello ati awọn mẹrin mii yoo se waye lonii .

Lati bii agogo meje owurọ lawọn eeyan ti n ya kẹti kẹti lọ ile ẹjọ, bẹẹ lawọn ẹṣọ alaabo duro wamu wamu si ọgba ile ẹjọ giga naa.

Igbejọ Abdulrahman Bello ati awọn mẹrin mii ti wọn fi ẹsun ipaniyan kan lo ti bẹrẹ lati inu osu keji ọdun yii lori ẹsun pe wọn sekupa Hasfot Yetunde Lawal ni ilu Ilọrin.

Asekagba idajọ bẹrẹ laago mẹsan kọja diẹ laarọ oni alamisi ọjọ kọkanlelọgbọn osu Keje ọdun yii
Adajọ Christiana Ajayi bẹrẹ kika igbẹjọ rẹ lago mẹsan kọja isẹju mẹwa.

Lẹyin o rẹyin, o da awọn afurasi mẹrin to n jẹjọ pẹlu Abdulrahman Bello silẹ, pe ki wọn maa lọ sile ni alaafia tori wọn ko mọ ohunkohun nipa ẹsun ipaniyan naa.

Amọ o wa sọ Abdulrahman si ẹwọn ọdun mẹwa lori ẹsun pe o ni ẹran ara ati ẹjẹ eeyan nikawọ rẹ.

Adajọ Ajayi si tun pasẹ pe ki wọn yẹgi fun Abdulrahman lori ẹsun ipaniyan ti wọn fi kan an tori oun lo pa Yetunde Hafsot.
Lasiko to n gbe idajọ rẹ kalẹ, Adajọ Christiana Ajayi to gbọ ẹni ọhun se atupalẹ idajọ rẹ wẹlẹwẹlẹ.

Adajọ naa ni “Lara ẹsun ti wọn fi kan iwọ Abdulrahman Bello ni pe o pa Hasfot Lawal o si ge ẹya ara rẹ.

Adajọ Christiana ni awọn ẹlẹri jẹri tako iwọ Abdulrahman Bello gẹgẹ bi ẹri tawọn agbofinro mu wa ile ẹjọ gẹgẹ bi ẹsẹ ofin ti laakalẹ.

Gẹgẹ bi ofin ijọba ipinlẹ Kwara to de iṣẹlẹ ijinigbe ati awọn iwa ọdaran mi.

Awọn agbofinro lati agọ ọlọpaa ọjọ ọba Ilorin ṣiṣẹ lori Hasfot Yetunde Lawal to dawati, lẹyin ti baba ọmọ naa, ọgbẹni Adefalu ti fi ẹjọ sùn lagọ ọlọpaa pe, oun ko ri ọmọ oun.

Awọn agbofinro bẹrẹ iwadii wọn, ti wọn si ri pe, ile iwọ Abdulrahman Bello ni Hasfot Yetunde Lawal wa.

Ìwádìí awọn agbofinro fi han pe, iwọ lo pe e lọjọ kẹtala oṣu keji ọdun yii wa si ile rẹ, gbogbo awọn mẹrin to ku, to n jẹjọ́ pẹlu rẹ, ko mọ kankan nípa ẹsun ti wọn fi kan wọn.”

Bakan naa, o ni Abdulrahman Bello ni awọn mẹrin to ku ti wọn dijọ fẹsun ipaniyan kan, ko mọ kankan nipa iṣẹlẹ naa, eyi si ni igba akọkọ ti oun yoo pa eeyan .

Adajọ Ajayi wa da wọn lare pe, ki wọn ma lọ ni idalare lai gba ijiya ẹsẹ kankan.
Lẹyin to gbe idajọ akọkọ naa kalẹ, Adajọ Christiana Ajayi wa mẹnu le ijiya ẹsẹ Abdulrahman.

Adajọ tẹsiwaju pe lẹyin ti Hasfot Yetunde Lawal de ile Abdulrahman Bello tan, ni o fi tipatipa ba lọ pọ.

“Fọ́nrán fidio ti ASP Daisi mu wa ile ẹjọ ati ọlọpaa Ayọdele lati ẹka otẹlemuyẹ fihan bi iwọ Abdulrahman Bello se jẹwọ fun wọn nipa isẹlẹ naa, ti eyi si jẹ ẹrí niwaju ile ẹjọ.

Bakan naa, ẹri ọrọ ẹnu rẹ ti agbẹjọro kọ kalẹ lọdọ awọn ọlọpaa tun safihan rẹ pe, o jẹri si pe iwọ lo pa Hasfot Yetunde Lawal.

Ninu iwe ti wọn fi gba ọrọ ẹnu rẹ silẹ lori iṣẹlẹ naa, wọn bi iwọ Abdulrahman Bello lere pe, n jẹ o ni ohun kan mii ti o fẹ fi kun ọrọ rẹ, o si sọ pe rara.”

Adajọ Christiana Ajayi ni gbogbo fọnran fidio ti wọn ti fi ọrọ wa ọ lẹnu wo lagọ ọlọpaa ni olopaa Ayodele Joshua mu wa ile ẹjọ.

Adajọ sọ pe pẹlu ẹri ti awọn ọlọpaa agbefọba mu wa si ile ẹjọ fihan pe, Abdulrahman lo pa Afsot .
Adajọ naa tun tẹsiwaju ninu alaye rẹ pe nigba ti awọn ẹlẹri ile iwosan n jẹri ni ile ẹjọ, ẹri wọn fihan pe, ẹya ara Hasfot Yetunde Lawal ni wọn gbe wa si ile ẹjọ.

“Niwaju gbogbo ile ẹjọ ni wọn ti ṣafihan fọnran fidio ti awọn ọlọpaa mu wa, nibi ti wọn ti ri Ada, Ọbẹ, aake, rọba, oogun, tabili ti ẹjẹ wa lori rẹ ninu ile rẹ.

Ninu fọnran fidio naa ni wọn ti ri ọwọ meji to jẹ ti oloogbe naa, ti iwọ Abdulrahman Bello ko si jiyan rẹ.

Ọlọpaa agbefọba sọ fun ile ẹjọ pe ni kete ti wọn de ile iwọ Abdulrahman Bello ni wọn ri bata ati ẹrọ ibanisọrọ Hasfot Yetunde Lawal pẹlu yẹti eti rẹ, ẹjẹ ati ẹya ara oloogbe naa pẹlu ọti lile.

Iwọ Abdulrahman Bello si sọ niwaju ile ẹjọ pe bi o se mu ọti lile tan, lo pa Hasfot Yetunde Lawal nitori lasiko igba naa ko si ẹni ti o ko lepa.

Awọn ọlọpaa ṣafihan fọnran fidio ibi to ti mu wọn lọ ile ilẹ ni agbegbe Oko Olowo, ni ibi to ju ẹya ara Hasfot Yetunde Lawal to ku si.

Ni agbegbe Oko Olowo yii si ni won ti pada ri ẹya ara Hasfot to ku nibi ti wọn ti ri itan, aya, ẹsẹ ati awọn ẹya ara mi.

Ti wọn si gbe le ọ lọwọ nibi ti wọn ti ya foto rẹ ati fọnran fidio, ti wọn si bi ọ lere pe ki lo gbe dani, o sọ pe ẹya ara Hasfot Lawal ni.

Ninu fọnran fidio ti wọn mu wa si Ile ẹjọ, wọn ri ìgbà, ẹjẹ ninu rọba, bata, ati asọ to ti yi pada di ẹjẹ eyi ti awọn ọlọpaa ni o jẹ irubọ.

Ninu ẹri ni ile ẹjọ wọn salaye bi o ṣe da ọti líle sinu ọwọ Hasfot mejeeji ti wọn ri ninu ile rẹ, ọ si sọ fun awọn ọlọpaa pe o fẹ fi ṣe ajo owo ni.”
Adajọ Christiana Ajayi salaye pe ẹri ayẹwo awọn Dokita ile iwosan nla UITH Ilọrin, fihan pe ẹya ara eeyan ni ohun ti awọn ọlọpaa ba ninu ile Abdulrahman.

“Dr Folaranmi ni ile iwosan nla UITH Ilọrin ,fi ẹri han ni ile ẹjọ pe ẹya ara Hasfot ni awọn ọlọpaa ri ninu ile rẹ.

Ẹri naa fihan pe iwọ Abdulrahman Bello jẹ ọdaju eeyan, apamọ lẹkun jaye

Orẹ Hasfot Yetunde Lawal naa jẹri ni waju ile ẹjọ bi Hasfot se dawati.

Abdulrahman Bello naa tun sọ fun ile ẹjọ pe nigba ti o ko le e da oku Hasfot Lawal gbe, lo lọ mu ọti lile, lẹyin naa lo ge oku rẹ wẹlẹwẹlẹ lati lọ danu.

“Abdulrahman salaye fun ile ẹjọ pe oun lo oogun to n mu nnkan ọkunrin le lati ba Afsot lopọ ni tipa”

Adajọ Ajayi wa salaye pe Abdulrahman Bello sọ fun ile ẹjọ lori pe o kabamo iwa ibi naa nitori o ti ba orukọ alfa ati mọlẹbi rẹ jẹ.”
Adajọ salaye pe Ọmọwe Adebọwale, to jẹ ajafẹtọ ọmọniyan, naa tun jẹri ni ile ẹjọ nipa awọn oun ti Abdurahman Bello ti sọ niwaju rẹ.

O ni Adebowale sọ fun ile ẹjọ pe ọti líle to mu lo, lo ti ọ ni itikuti to fi pa Hasfot Yetunde Lawal.

“Gbogbo awọn ẹri to wa niwaju ile ẹjọ giga yii fihan pe ọdaju eeyan ni ọ, ti o ba jẹ pe lootọ lo nifẹ oloogbe, to si fẹ fi se aya, o ni dẹmi rẹ legbodo .

Ṣugbọn a dupẹ lọwọ Ọlọrun to tu gbogbo asiri wọnyii, eyi fihan pe lootọ ni iwọ Abdulrahman Bello pa Hasfot Yetunde Lawal.

Iwa ọdaju gba a lo jẹ pe o pa Hasfot, lẹyin to pa tan, o tun lọ ibi ayẹyẹ inawo bi igba pe o ko ṣe kankan, a fi igba ti ọwọ ọlọpaa to tẹ.

Nitori eyi o jẹbi ẹsun ipaniyan.”

Lori ẹsun ipaniyan naa, ile ẹjọ pasẹ ki wọn yẹgi fun Abdulrahman Bello.

Lori ẹsun nini ẹya ara eeyan nikawọ ati ẹjẹ, ile ẹjọ pasẹ ki Abdulrahman Bello lọ ẹwọn ọdun mẹwa ati owo itanran ẹgbẹrun lọna ọgọrun kan naira.

Lori ẹsun ifipabanilopo adajọ ni Abdulrahman ko jẹbi nitori ko si ẹri fun.

Ayajọ ololufẹ to maa n waye lọjọ kẹrinla oṣu Keji odun ku dẹdẹ ni iroyin iku ọdọbinrin kan, Hafsoh Yetunde Lawal, gba ori ayelujara kan.

Iroyin naa sọ pe ọmọbinrin yii lọ sile ọrẹkunrin rẹ niluu Ilọrin, ati pe ibẹ lo ti pade iku ojiji ti ko si le wale mọ.

Baba to bi Hafsoh, Ọgbẹni Adefalu Lawal, lo pada lọọ fi iṣẹlẹ naa to ileeṣẹ ọlọpaa leti, lẹyin ọjọ kan ti wọn ti n wa a titi ti wọn ko ri i.

Lẹyin to de etigbọọ awọn ọlọpaa ni wọn tọpasẹ ẹrọ ibanisọrọ Hafsoh de ọdọ ọkunrin kan, Abdulrahman Bello.

Ọlọpaa to ṣoju ijọba to si jẹ ẹlẹrii keji nigba ti ọrọ naa pada de kootu, ṣalaye pe lọjọ kẹwaa, oṣu Keji ọdun 2025 ni ọkunrin kan ti wọn pe ni Adefalu Lawal, wa fi to awọn leti lagọ ọlọpaa Ọja Ọba, niluu Ilọrin, pe oun n wa ọmọ oun, Hasfoh Lawal to jade ti ko si pada wọle mọ.

O fi kun pe awọn tọpaṣẹ ẹrọ ibanisọrọ Hasfoh de ọdọ Abdurahman nitori oun lo pe e gbẹyin lọjọ naa.

Lọjọ kẹrinla, oṣu Keji lọwọ tẹ ọkunrin kan ti wọn pe ni Abdurahman Bello, lagbegbe Isalẹ Koto, niluu Ilọrin.

O ni Abdurahman mu awọn ọlọpaa lọ sile rẹ lọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Keji.

Ọlọpaa naa fi kun un pe oju ọna Ọffa Garage lawọn de ti Abdurahman Bello fi jẹwo fawọn pe oun ti pa Hasfoh Yetunde Lawal, o ni ṣugbọn kawọn ma sọ fun ẹnikẹni.

Ọlọpaa naa sọ pe Abdulrahman fi owo ẹyin lọ awọn lọjọ naa, lati bo aṣiri rẹ.

O ni lẹyin naa ni awọn lọ sile rẹ, nibi ti awọn ti ri bata Yetunde ati ẹrọ ibanisọrọ rẹ meji.

“Nigba ti a wọ yara la ri ada to ni ẹjẹ lara, ọbẹ, rọba ti o rọ ẹjẹ si, ati ike ọda nibi ti ọwọ mejeji ti wọn da ogogoro si wa. O si jẹwọ pe oun pa a lati fi ṣe ogun owo ni.”

Ọlọpaa ni Abdurahman yii kan naa lo mu awọn lọ si agbegbe Oko-Olowo, nibi ti o ju ẹya ara to ku si.

Bo tilẹ jẹ pe Abdulrahman figba kan ṣalaye bakan naa ni kootu pe oun fun Yetunde lọrun lẹyin ibalopọ titi to fi ku, nitori koun le fi ẹya ara rẹ ṣowo.

O yi ohun pada laaye kan, o ni oun kọ loun pa Oloogbe naa.

Abdulrahman Bello sọ pe ikọ seemi-seemi ti i ṣe Asthma lo pa Yetunde, nigba toun ko si le da oku rẹ gbe jade nile loun kun un wẹlẹwẹlẹ.

Ẹni ọdun mejilelogun ni wọn pe Oloogbe Hafsoh Lawal, ipele to gbẹyin lo si wa nileewe ẹkọṣẹ awọn olukọ, n’Ilorin.

Ode isọmọlorukọ ọrẹ rẹ kan ni iroyin sọ pe o ti kuro lọjọ to di awati, to gba ile Abdulrahmon lọ ti ko si pada sile awọn obi rẹ mọ.

Ki wọn too mọ pe o ti ba iku ojiji pade ni.