Ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ yóó bẹ̀rẹ̀ ìyanṣẹ́lódì

Ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ yóó bẹ̀rẹ̀ ìyanṣẹ́lódì

Fẹ́mi Akínṣọlá

Bí ọ̀rọ̀ táwọn olórí ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ lórílẹ̀-èdè wa ń sọ bá jẹ́ òótọ́, Ọjọ́rú, ọjọ́ keje, oṣù Kẹfà, ọdún 2023 yìí, ni wọ́n sọ pé àwọn yóó bẹ̀rẹ̀ ìyanṣẹ́lódì jákè-jádò orílẹ̀èdè yìí, nítorí ọrọ̀ owó ìrànwọ́ epo bẹntiróòlù tíjọba àpapọ̀ kéde rẹ̀ pé àwọn ti yọ kúrò, èyí tó ti mú kí gbogbo nǹkan gbówó lórí, tí àwọn aráàlú sì ń kojú ìnira ńlá.

Àtẹ̀jáde pàtàkì kan tí Akòwé àgbà àjọ náà, Kọmureedi Emmanuel Ugboaja, fi léde lẹyìn ìpàdé ẹgbẹ́ náà, èyí tó wáyé lọ́jọ́ Ẹtì, ọjọ́ kejì, oṣù Kẹfà, ọdún yìí, ní wọ́n ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé kò sóhun tó lè dí àwọn lọwọ́ láti má ṣe bẹrẹ ìyanṣẹ́lódì náà lọ́sẹ̀ yìí bíi ìpinnu àwọn olóyè ẹgbẹ́ náà lórí ọhún tí ìjọba àpapọ̀ ṣe nípa bí wọ́n ṣe yọwó ìrànwọ́ lórí epo bẹntiróòlù kúrò.

Bákan náà ni wọ́n rọ gbogbo àwọn olórí ẹ̀ka iléeṣẹ́ gbogbo tí wọ́n jẹ́ ojúlówó ọmọ ẹgbẹ́ àjọ òṣìṣẹ́ nílẹ̀ yìí pé kí wọ́n gbárùkù ti ètò náà, kó baà lè kẹ́sẹjárí láyọ̀ àti àlàáfíà báyìí.

Apá kan lẹ́tà ọ̀hún sọ pé: ‘A ti gbé e yẹ̀wò dáadáa, ìgbésẹ̀ ìjọba àpapọ̀ lórí bó ṣe yọwọ́ ìrànwọ́ lórí epo bẹntiróòlù ọ̀hún kìí ṣohun tó dáa rárá, a kò ní í gbà fún wọn, bí ìjọba kò bá tètè yí ìpinnu rẹ̀ padà lórí ọ̀rọ̀ náà, gbogbo òṣìṣẹ́ nílẹ̀ yìí pátá ni wọn yóó gùn lè ètò ìyanṣẹ́lódì lọ́sẹ̀ tó ń bọ̀. Kò sóhun náà tó lè dá wa dúró rárá pé ká má bẹ̀rẹ̀ ìyanṣẹ́lódì. À ń fi àsìkò yìí rọ gbogbo àwọn ojúlówó àjọ òṣìṣẹ́ nílẹ̀ yìí pé kí wọ́n wà ní ìgbaradì fún ètò náà lọ́sẹ̀ tó ń bọ. Jákè-jádè orígun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin orílẹ̀-èdè yìí ní àwọn òṣìṣẹ́ yóó ti daṣẹ́ sílẹ̀.’

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here