Egbẹ́ òṣìṣẹ́ NLC,TUC fárígá kéde ìyanṣẹ́lódì ọlọ́jọ́ gbọọrọ

Egbẹ́ òṣìṣẹ́ NLC,TUC fárígá kéde ìyanṣẹ́lódì ọlọ́jọ́ gbọọrọ

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ó ti pẹ́ tí àwọn èèyàn ti máa n sọ pé èdè kan ṣoṣo tí ìjọba gbọ́ kò ju ìyanṣẹ́lódì lọ, ní báyìí àgbáríjọpọ̀ ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ Nàìjíríà Nigeria Labour Congress, NLC àti Trade Union Congress, TUC ti panupọ̀ kéde pé àwọn yóó gùnlé ìyanṣẹ́lódì ọlọ́jọ́ gbọọrọ ní Nàìjíríà.

Ìkéde yí wáyé lẹ́yìn ìpàdé tí wọ́n ṣe lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun tí wọ́n sì fẹnukò pé bẹ̀rẹ̀ láti ọjọ́ Ìṣẹ́gun ọjọ́ Kẹta oṣù Kẹwàá 2023 àwọn yóó bẹ̀rẹ̀ ìyanṣẹ́lódì náà.

Ṣaájú ní wọ́n ti fún ìjọba ní gbèdéke ọjọ́ méjìlá àti ìyanṣẹ́lódì ìkìlọ̀ ọlọ́jọ́ méjì láti fi jẹ́ kí ìjọba wá nǹkan ṣe sí ìnira tó dé ba aráàlú lẹ́yìn tí ìjọba yọ ẹ̀kúnwó epo bẹntiróò.

Ààrẹ NLC àti ti TUC Comrade Joe Ajaero àti Comrade Festus Osifo ló jọ buwọ́lu àtẹ̀jáde tó tẹ̀yìn ìpàdé yìí wáyé.

Wọ́n ní ní ìbámu pẹ̀lú àyájọ́ òmìnira Nàìjíríà àwọn náà ṣetán láti rí pé òmìnira tó péye fáwọn aráàlú nípa gbígba arawọn sílẹ̀ àti mímú àyánmọ́ arawọn ṣe fún ara wọn.

Ní báyìí ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ láwọn tikésí gbogbo àwọn ẹ̀ka ẹgbẹ́ náà láti bẹ̀rẹ̀ ìpalẹ̀mọ́ láti yan iṣẹ́lódì kí wọn sì gba ìgboro kan pẹlú ìwọ́de títí tí ìjọba yóò fi tẹ́tí sí àwọn ẹ̀dùn ọkàn táwọn fi ṣọwọ́.

Nínú ọ̀rọ̀ tí NLC àti TLC sọ nínú àtẹ̀jáde tí wọ́n fi síta, wọn ní kókó pàtàkì ni pé àti àwọn ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ àti ìjọba àríyànjiyàn kò sì lórí pé yíyọ ẹ̀kúnwo epo bẹntiró mú kí ara máa ni aráàlú púpọ̀.

Àmọ́ wọ́n ní ìjọba kọ̀ láti gbé ìgbésẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ojúṣe wọn èyí tí yóó mú ìnira ẹbi àti òṣì tó kárí yìí dínkù láwùjọ.

”Ìjọba àpapọ̀ kàn dá ọgbọ́n lórísìí láti fọ̀rọ̀ jomi toro ọ̀rọ̀ pẹ̀lú ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ ní láti lè mú ìdẹ̀kùn bá aráàlú nítorí ẹ̀dínwó epo tí wọ́nyọ.”

Àwọn ẹgbẹ́ náà tẹ̀síwájú pé ìjọba kó fi ọ̀nà kankan tó bójúmu wá nǹkan ṣe sí àwọn ẹ̀dùn ọkàn ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ àti aráàlú gẹ́gẹ́ bí ó ṣe wà nínú ìlànà àjùmọ̀fẹnukò sí ti yóó mú kí ara dẹ aráàlú.

Torí náà àwọn olórí ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ ti wá sọ pé gbogbo ọ̀nà ni ìjọba ń gbà láti sọ ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ lẹ́nu pàápàá lójú òpó ayélujára tí wọ́n sì ń lo agbára wọn láti fún àwọn lọ́rùn dípò kí wọ́n fi agbára ọ̀hún mú ayé dẹrùn fáráràlú.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here