Ẹ yéé gba ríbà lọ́wọ́ ọ̀daràn: Alága EFCC kìlọ̀ fáwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀

Ẹ yéé gba ríbà lọ́wọ́ ọ̀daràn: Alága EFCC kìlọ̀ fáwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀


Fẹ́mi Akínṣọlá
Àwọn àgbà ní èèyàn tí yóó fọ àwùjọ mọ́, yóó fọ yóó fọ araarẹ̀ pẹ̀lú mọ́ ọ.
Èyí ló bí bí Ọ̀gá àgbà àjọ tó ń gbógun ti ìwà ìbàjẹ́ àti ṣíṣe owó ìlú mọ́kumọ̀ku nílẹ̀ wa, ‘Economic And Financial Crimes Commission’ (EFCC), ṣe ṣèkìlọ̀ pàtàkì fáwọn òṣìṣẹ́ àjọ ọ̀hún tó jẹ́ pé wọ́n máa ń gba r’íbà lọ́wọ́ àwọn afurasí ọ̀daràn gbogbo tí wọ́n ń ṣèwádìí nípa wọn lọ́wọ́ láti lè dójú ẹjọ́ wọ́n rú pé kí wọ́n jáwọ́ nínú irú ìwà bẹ́ẹ̀.

Ọla Olukayọde tó jẹ́ adarí wọ́n ló sọ̀rọ̀ ọ̀hún di mímọ̀ lásìkò tó ń ṣèpàdé àkọ́kọ́ nínú ọdún pẹ̀lú wọ́n ni olú ilé-iṣẹ́ wọn tó wà ní Jabi, nílùú Àbújá, l’Ọ́jọ́bọ, ọjọ́ kejìdínlógún, oṣù Kìn-ín-ní, ọdún 2024 yìí.

Ó ní nǹkan ìdójútì gbáà ni pé àwọn òṣìṣẹ́ àwọn ń lọ́wọ́ nínú irú ìwà bẹ́ẹ̀ . Ó fi kún-un pé lásìkò ìṣèjọba tòun yìí, òun kò ní gba irú ìwà bẹ́ẹ̀ láàyè. Olukayọde ni tí àwọn òṣìṣẹ́ àjọ ọ̀hún tí wọ́n kúndùn irúfẹ́ ìwà láabi ọ̀hún kò bá sì jáwọ́ nínú ìwà pálapàla bẹ́ẹ̀, ẹni tí òfin bá gbá mú yóó kábàámọ̀ ìwà burúkú tó hù náà.

Ó ní, ‘‘ Ó ti tó àkókò fún mi báyìí láti ṣe ìtẹnumọ́ lórí ìwà kíkọ ara ẹni ní ìjánu, àti fífi ìwà ọmọlúàbí ṣiṣẹ́ wa. Ojú tí àwọn aráàlú fi ń wo ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn wa tó máa ń ṣe iṣẹ́ ìwádìí kì í ṣe èyí tó dáa rárá. Ìṣọwọ́ bèèrè r’íbà àtàwọn owó tí kò bófin mu bẹ́ẹ̀ ti ń mú ìtìjú bá iṣẹ́ wa, kò sì yẹ kó tẹ̀síwájú bẹ́ẹ̀. Ẹ jẹ́ kí ń tún fi àsìkò yìí ṣe ìkìlọ̀ gidigidi pé mi ò ní i rò ó lẹẹmeji tí má a fi fi idà òfin gé ẹnikẹ́ni tó bá hu irú ìwà yìí lọ́wọ́ tí ọwọ́ bá ti tẹ̀ ẹ́.

‘‘Mo ti sọ fún ẹ̀ka tó ń mójútó ọ̀rọ̀ abẹ́lé pé kí wọ́n jí gìrì sí iṣẹ́ wọn lórí eléyìí, kí wọ́n sì máa sọ́ àwọn òṣìṣẹ́ lórí ìgbésẹ̀ gbogbo tí wọ́n bá ń gbé nípa iṣẹ́ wọn. Orúkọ àjọ yìí ṣe pàtàkì ju kí òṣìṣẹ́ alájẹbánu kan wá bà á jẹ́ lọ’’

Bẹ́ẹ̀ ló fi kún un pé àwọn ti ń gbé ìgbésẹ̀ láti wá nǹkan ṣe sí ọ̀rọ̀ ìgbáyé-gbádùn àwọn òṣìṣẹ́ yìí.

.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here