Ẹ wá ìmọ̀ tó péye fún ìwé ẹ̀rí tó yanrantì—Ọ̀jọ̀gbọ́n Gbọ́lágadé
Fẹ́mi Akínṣọlá
Àmọ̀ràn ti lọ sọ́dọ̀ àwọn èèyàn làti má a wá ìmọ̀ ojúlówò èyí tí yóó ṣe onímọ̀, àwọn tó yí i ká àti àwùjọ láǹfànì ayérayé.
Ọ̀rọ̀ ìyànjú yìí ló jẹyọ lẹ́nu
Aṣojúdárí ilé ẹ̀kọ́ náà “Provost” Ọ̀jọ̀gbọ́n Gbọ́lágadé Abíọ́dún Táíwó, tó ń dárí ẹ̀ká Fásitì Adekunle Ajasin tó wà ní ọgbà Mufutau Lanihun Ọremeji Ìbàdàn,lórúkọ Fásitì ọ̀hún tó wà ní ìpínlẹ̀ Òndó,lábẹ̣̀ Ọ̀jọ̀gbọ́n Olugbenga Ige, lásìkò tó ń gbé ọ̀rọ̀ ìmọ̀ràn kalẹ̀ fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́, akòwé àgbà ilé- ẹ̀kọ́ náà tó ṣojú Ọ̀jọ̀gbọ́n Gbọ́lágadé Abíọ́dún Táíwó , Ṣheik Adébólú Sirajudeen fi iṣẹ jẹ pé, ìwúrí nlá ló jẹ́ fún òun pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà ṣàmúlò ẹ̀kọ́ tí wọ́n kọ́ lọ́gbà Fásitì ọ̀hún.
Ó tẹ̀síwájú pé, ìtàn kìí parẹ́ , àti pé, ìtán ni wọ́n n kọ yìí fún àwọn ìran tì yóò kẹ́kọ̀ọ́ gboyè lọ́gbà Fásitì yìí.
Ọ̀jọ̀gbọ́n Gbọ́lágadé Abíọ́dún kádìí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé ,wọ́n ti bomi ọgbọ́n mu níbi tí odò ìmọ̀ gbé jìngòdò, látàrí èyí,kí wọ́n fọ́n sìnú àyé lọ fi orúkọ Fásitì yìí yàwòrán rere fún gbogbo àgbáálayé.