Ẹ máà pín owó rìbá yín kàn mí, ọ̀gá àgbà ọlọ́pàá kìlọ̀ f’áwọn ọlọ́pàá

Ẹ máà pín owó rìbá yín kàn mí, ọ̀gá àgbà ọlọ́pàá kìlọ̀ f’áwọn ọlọ́pàá
Fẹ́mi Akínṣọlá
Ṣé wọ́n ní ọlọ́tọ̀ ní tòun ọ̀tọ̀, Ọ̀gá àgbà iléeṣẹ́ ọlọ́pàá orílẹ-èdè Nàìjíríà, Kayode Egbetokun ti fi ọ̀rọ̀ léde  pé òun kò retí kí ọlọ́pàá kankan pín owó kan òun pẹ̀lú àlàyé pé ojúṣe tí òfin là kalẹ̀ fún iléeṣẹ́ ọlọ́pàá nìkan ló yẹ kó jẹ wọ́n lógún.
Igbákejì ọ̀gá àgbà iléeṣẹ́ ọlọ́pàá láti ẹkùn ikọkanla tó jẹ́ iṣẹ́ náà lásìkò àbẹwò sí olú iléeṣẹ́ ọlọ́pàá tó ń bẹ nílùú Ìbàdàn, olú ìlú ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ l’Ọ́jọ́rú, Paul Ojeka Odama   pàrọwà si gbogbo òṣìṣẹ́ iléeṣẹ́ ọlọ́pàá láti dẹ́kun gbogbo ìwà tí  ó lè ta ẹrẹ bá aṣọ àlà iléeṣẹ́ náà.
Ó ní, “Iṣẹ́ tí ó lọ́lá nínú ni iṣẹ́ ọlọ́pàá, tí ó sì dúró fún ìdájọ́ òdodo àti àlàáfíà. Agbófinró tuntun ti wọ ìlú, òun sì ni ọ̀gá àgbà tuntun fún iléeṣẹ́ ọlọ́pàá. Gbogbo ìgbà sì ló máa ń fi ikorira hàn sí ìwà  àjẹbánu.
Àpẹrẹ rere ló máa ń jẹ́ ní gbogbo ibi tí  ó bá ti ṣiṣẹ́. Àkọsílẹ̀ àwọn ìwà náà ń bẹ n’íìpínlẹ̀ Kwara níbi tó ti ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bíi Kọmísánà àjọ ọlọ́pàá àtí àwọn  ibòmíì tí ó ti ṣiṣẹ́.”
Ọlọ́pàá tó bá mọ nǹkan tó ń ṣe kò ní báwọn gba r’íbà – Ọ̀gá àgbà ọlọ́pàá Nàìjíríà ṣe àlàyé pé iṣẹ́ ni wọ́n rán gbogbo ọlọ́pàá láti ṣe n’ígboro, bẹ́ẹ̀ sì ni kìí ṣe láti pa owó wọlé fún ẹnikẹ́ni gẹ́gẹ́ bí òfin orílẹ-èdè Nàìjíríà ti ọdún 1999 ṣe làá kalẹ.
Ọ̀gá àgbà iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ní òṣìṣẹ́ àjọ náà tí ó bá mọ ohun tí ó ń ṣe kò ní bá wọn gba owó ìbọ̀bẹ́ lọ́wọ́ ọlọ́kadà tàbí awakọ̀ kankan.
Ó ní ìwà ìbàjẹ́ tí  ó gbudọ̀ dópin ni bí awakọ̀ ṣe ń gba owó lọ́wọ́ èrò ọkọ̀ láti fún ọlọ́pàá tó dènà ọkọ̀ nítorí owó ẹ̀yìn.
Egbetokun ní gbogbo òṣìṣẹ́  iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ló gbudọ̀ ṣe iṣẹ́ wọn pẹ̀lú ìbẹrù Ọlọ́run kí wọ́n sì tẹ̀lé òfin ìjọba lẹ́nu iṣẹ́ wọn.
Bákan náà ló  ké sí àwọn ọlọ́pàá láti ṣọ́ra fún irúfẹ́ ìròyìn tí wọ́n ń pín kiri lórí ayélujára. Ó ní wọ́n gbúdọ̀ ṣe àyẹ̀wò fínífíní kí wọ́n tó pín ohunkóhun kiri lórí ìtàkùn àgbáyé.
Ọ̀gá àgbà iléeṣẹ́ ọlọ́pàá tún mẹ́nuba pàtàkì ìmúra àwọn ọlọ́pàá àtí bí wọ́n ṣe ń wọ aṣọ wọn lẹ́nu iṣẹ́ àti nígbà tí wọ́n bá ṣíwọ́ iṣẹ́, nítorí ìrínisí ni ìṣenilọ́jọ̀.
Tẹ́lẹ̀rí ni ìròyìn má a ń lọ káàkiri wí pé àwọn òṣìṣẹ́ ọlọ́pàá kan ti wọ́n ń hùwa ìbàjẹ́ n’ígboro tí wọ́n sì ń gba owó lọ́nà àìtọ́ ní àwọn ọ̀gá tí wọ́n n fi owó ọ̀hún jíṣẹ́ fún.
Ọ̀rọ̀ tí ọgá àgbà iléeṣẹ́ ọlọ́pàá fi léde fi hàn gbangba wí pé irú ìwà bẹ́ẹ̀ kò ní wáyé nínú ìṣàkóso tuntun yìí.