Ẹ gba àlááfíà láàyè, mìmì kan kò lè mìwá – Asíwájú Ahmed Tinubu

Ẹ gba àlááfíà láàyè, mìmì kan kò lè mìwá – Asíwájú Ahmed Tinubu

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé àwọn àgbàlagbà ní pẹ̀lẹ́ la fi í pàmúkùrù u pẹ̀lẹ́,bẹ́ẹ̀ wọ́n ti ní ọmọ onílù ú kan kò ní-ín fẹ́ kó tú lórí òun.
Olùdíje sípò ààrẹ ní ẹgbẹ́ òṣèlú APC, Asíwájú Bola Ahmed Tinubu ti késí àwọn ará ìpínlẹ̀ Èkó láti gba àlàáfíà láàyè.

Tinubu sọ èyí nínú àtẹ̀jáde tó fi léde nípa ìròyìn rògbòdìyàn tó bẹ́ sílẹ̀ ní àwọn agbègbè kan ní ìpinlẹ Èkó nítorí èsì ìdìbò sípò ààrẹ ní Nàìjíríà.

Lẹ́yìn tí wọ́n ní àwọn oní jàgídíjàgan kan ṣe ìkọlù sí àwọn ènìyàn tó wá láti ẹ̀yà ìgbò à mọ́ tí wọ́n ń gbé ní ìpínlẹ̀ Èkó.

Ó ní kí àwọn ará ìlú gba èsì ìdìbò ààrẹ tí INEC kéde níbi olùdíje sípò ààrẹ ní ẹgbẹ́ òṣèlú Labour party, Peter Obi ti borí ní ìpinlẹ Èkó gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ àwọn ènìyàn.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here