È̩mi kankan kò sòfò nìnú ìko̩lù òpópónà Abe̩okuta si Eko – Agbẹnusọ ọlọ́pàá.
Gbọ́láhàn Quseem
Lásìkò tí ó n fi íròyìn síta lórí ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún, SP Ọmọlọlá Odùtọ́lá tó jẹ́ agbẹnusọ ọlọ́pàá ní ìpínlẹ̀ Ògùn sọ pé, àwọn ti bẹ̀rẹ̀ si sèwadìí l’órí àwọn ajínigbé náà.
Odutọla ninu atẹjade naa ṣalaye pe, ọkunrin kan ni awọn ajinigbe ọhun tọpinpin rẹ de agbegbe ti ọna ko ti dara lopopona marosẹ ọhun, ko to di pe wọn yin ‘bọn mọ taya mejeeji to wa ni ẹyin ẹsẹ mọto rẹ lati le daa duro.
Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe “Ikọ agbebọn ti enikẹni ko le sọ pato iye wọn, ninu mọto Toyota Venza ti ko ni nọmba idanimọ, ni wọn tọpinpin ọkunrin kan to wa ninu mọto Toyota RAV4, alawọ eeru rẹ pẹlu nọmba idanimọ AGL-16-JE.
“Bi wọn ṣe de agbegbe ti ọna ko ti dara, ni wọn wa mọto dina mọ mọto ọkunrin naa.
“Awọn ọdaran naa yin ‘bọn ẹlẹnu mẹrin ti igbagbọ wa pe AK-47 ni wọn gbe dani, si taya ẹyin rẹ, ti wọn si tun yin ‘bọn fun taya iwaju.
Loju ẹsẹ ni wọn bọ silẹ, ti wọn si wọ ọkunrin ọhun bọ silẹ lati wọ inu mọto rẹ, ko to di pe wọn mori le ọna Ijẹbu-Ode.
“Lasiko ikọlu naa, awọn ọdaran yii tun yin ‘bọn fun awakọ Toyota Camry, alawọ dudu kan lẹsẹ lasiko to n gbiyanju lati yi pada, ko si salọ.
Bakan naa, wọn tun fọ gilaasi awakọ bọọsi kan to n rinrin-ajo lati Abuja lọ si Eko, ti wọn si gba foonu rẹ lọ, pẹlu ikilọ pe oun kọ ni wọn n wa.”
Odutọla fidi rẹ mulẹ pe, ko si ẹni to padanu ẹmi rẹ ninu ikọlu ọhun, ati pe, awọn mọto meji to bajẹ ninu ikọlu naa ni wọn ti wọ lọ sagọ ọlọpaa to wa nitosi.
O fi kun ọrọ rẹ pe ọga ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti gbọ si iṣẹlẹ naa, to si ti paṣẹ pe ki ikọ to n ri sọrọ ijinigbe bẹrẹ iṣẹ iwadi .