E̩gbé̩ òsèlú ADC nípínlè̩ Ogun ní èrú ni APC lò nínú àtúndì ìbò tó ko̩já
Mary Fágbohùn
Egbe Oselu ADC ti fi esun sise magomago kan APC ninu atundi ibo to waye lojo Abamẹta to kọja yii ni awọn ipinlẹ mẹtala ati ẹkun idibo mẹrindinlogun lorilẹede Naijiria.
Ninu esi ibo ti ajọ to n seto idibo, INEC, fi sita, o fi han pe APC bori ibo ni ẹkun idibo mejila, APGA bori ni ẹkun meji, PDP jawe olubori ni ẹkun kan, nigba ti NNPP naa jawe olubori ni ẹkun kan ṣoṣo.
Ṣugbọn o fẹrẹ jẹ pe kaakiri ipinlẹ ni awọn ẹgbẹ alatako ti bẹrẹ si i fi ẹhonu han lori esi idibo yii.
Wọn sọ pe APC lo agbara rẹ lati dena awọn ẹgbẹ yoku, pe wọn lo ipa ninu ijọba awarawa ni wọn fi yege.
Alaga ẹgbẹ oṣelu ADC ni nipinlẹ Ogun, Ọtunba Olufemi Soluade ninu alaye re̩ so pe egbe oselu re kopa ninu atundi ibo to waye fun ẹkun idibo Remo, Ikenne ati Sagamu lọjọ Abamẹta ọhun.
O tesiwaju ninu alaye re pe oludijẹ fun ẹgbẹ oselu ADC ko dibo. O ni APC lo agbara se e mọle ni.
“A ti dibo, ibo ti wa, o ti lọ, ṣugbọn ko lọ daadaa rara. Ninu ijọba awarawa ti a ni a n ṣe yii, ko yẹ ko ri bẹẹ. Ko yẹ ko jẹ ẹgbẹ kan lo maa sọ pe ki awọn ẹgbẹ to ku ma ni alaafia, ti yoo di pe awọn ọmọ ẹgbẹ ko ni i le dibo.
“A ti kọ lẹta ṣaaju idibo pe a maa dibo, a ka gbogbo ibi ti a maa de. A kọ lẹta si kọmiṣanna ọlọpaa Ogun, wọn fi ranṣẹ si ti Remo, wọn ti n ṣiṣẹ ẹ lori ẹ ki wọn too sọ fun wọn pe ki wọn ma sise lori lẹta wa.
“Mi o ro pe ẹgbẹ oṣelu kankan wa to buru bii APC, niṣe ni wọn n fi ọkọ akọtami le wa lọjọ ibo. Oludije ẹgbẹ oṣelu wa, Barrister Seyi Solomon Oso, ko raye dibo, niṣe ni wọn di i mọle, wọn gbe oko di enu ona abawole rẹ pa, wọn ko jẹ ko ribi jade lati le dibo.
“Bakan naa ni wọn gba gbogbo aga wa to wa nibi ti a ti fẹẹ dibo, iyẹn lo ku ọla ti a maa dibo.
“Ọlọpaa to to igba (200) ni wọn ko wa, wọn ni nnkan kan ko gbọdọ ṣẹlẹ nibudo ibo wa. Wọn ni APC nikan ni ibẹ wa fun, agidi la fi raye gbaa kọja.