È̩dítò̩ àkó̩kó̩ lóbìnrin, Doyin Abio̩la dolóògbé
Yínkà Àlàbí
Aarun lo se e wo, ko si e̩ni to le ri t’O̩lo̩jo̩ se.
Le̩yin aisan ranpe iku pa oju Dr Doyin Abio̩la ti se iyawo oloogbe Moshood Abiola de.
Mama yii je̩ O̩lo̩run nipe ni e̩ni o̩dun mejilelo̩go̩rin(82 years). Nigba aye re̩, oun ni dire̩kito̩ ile ise̩ iwe iroyin National Concord.
Mama yii ni obinrin ako̩ko̩ to di e̩dito̩ iwe iroyin olojoojumo̩ ni orileede yii.
Ede Ge̩e̩si ati ere ori itage ni e̩ko̩ ti mama ko ni Fasiti Ibadan ni o̩dun 1969.
Ileese̩ iwe iroyin Daily Sketch ni mama yii ti be̩re̩ ise̩ iroyin ki o kan National Concord le̩yin naa ni dr Doyin Abio̩la di Managing director ti National Concord ti se ti ologbe MKO Abio̩la.
A bi Doyin Abiola ni odun 1943 ki o̩lo̩jo̩ to de ni ale̩ ana.