Dotun Sanusi fúnra rẹ̀ sọ̀rọ̀ lórí oyè tó jẹ

Dotun Sanusi fúnra rẹ̀ sọ̀rọ̀ lórí oyè tó jẹ

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àwọn àgbà ní ohun a fẹ̀sọ̀ mú kì í bàjé.
Lọ́jọ́ Aiku ọ̀sẹ̀ yìí ni Ooni Adeyeye Ogunwusi (Ojaja Kejì), fi Olóyè Dotun Sanusi jẹ oyè.

Alààyé tó wà nínú oyè náà ni pé Ọ̀kanlọmọ Oòduà ni Ọọ̀ni fi Dọ̀tun Sànúsí jẹ.

Kì í ṣe Ọ̀kanlọmọ Ilẹ̀ Yorùbá ti igun Aláàfin Ọ̀yọ́ torí rẹ̀ ní kí wọ́n gba oyè ọ̀hún padà.

Gẹ́gẹ́ bí Dọ̀tun Sànúsí fúnra rẹ̀ ṣe kéde lójú òpó ayélujára rẹ̀, ó ní

” Àpọ́nlé ńlá ló jẹ́ fún mi láti kéde pé wọ́n ti fi mí jẹ oyè Ọkanlọmọ ilẹ̀ Oòduà, láti ọwọ́ Oọ̀ni Ilé Ifẹ̀, Ọba Ẹnìtàn Adéyeyè Ògúnwùsì. (Ọ̀jájá 11).

Sanusi tẹ siwaju pe nibi eto kan ti Ọonirisa gbe kalẹ, iyẹn oju opo iṣẹmbaye ti wọn ṣe lọna ẹrọ igbalode, ni wọn ti fi oye naa da oun lọla.

‘2GEDA’ ni wọn pe orukọ agbekalẹ naa, ilu Ibadan ni ifilọlẹ rẹ si ti waye.

Iwadii fi han pe ajọṣepọ ọlọdun pipẹ lo wa laaarin Ooni Adeyeye Ogunwusi ati Dotun Sanusi.

Iroyin si sọ pe ọdun karun-un ree ti Ooni ti fi oye naa sọri Dotun Sanusi, wọn ko wulẹ wuye naa nitori arun Corona to gbode nigba naa ni.

Lọjọ Aiku ọsẹ yii ni Ooni Adeyeye Ogunwusi (Ojaja Keji), fi Oloye Dotun Sanusi jẹ oye.

Alaaye to wa ninu oye naa ni pe Ọkanlọmọ Oodua ni Ọọni fi Dotun Sanusi jẹ.

Ki i ṣe Ọkanlọmọ Ilẹ Yoruba ti igun Alaafin Oyo tori rẹ ni ki wọn gba oye naa pada.