Dapo Abiodun rọ̀jò owó lé ilé ìwé giga MAPOLY àti àwọn akẹ́kọ̀ọ́ mẹ́sàn-án tó yege jùlọ lori

Gomina Ipinle Ogun, Alagba Dapo Abiodun, derin peeke awon alase, awob obi ati omo ile eko gbogbo-nse Moshood Abiola Polytechnic (MAPOLY) lojo Isegun to lo, nigba to kede ipese  bilionu meji naira (N2bn) fun idagbasoke fun ile-iwe naa.

Asiko ti won n se ayeye ikekojade ni Abiodun ju iroyin ayo naa sile.

Bakan naa, o kede milionu meji ataabo fun okookan awon akekojade mesan-an ti won se daadaa ju.

Se bi eegun eni ba n joore, ori a maa ya atokun.

Gomina kedun pe MAPOLY, to je ileewe to ti goke agba tele, ri ifseyin nigba ti Gomina tele, iyen Senato Ibikunle Amosun, gbe e lo si Ipokia.

O ni ileewe to ti maa n ni to omo bii ogbon egberun wa di eyi to n lakaka lori egberun marun-un.

O wa fi kun un pe nnkan ti n pada senu rere fun MAPOLY, tori o ti ni omo to egberun metala.