Dangote yọ N30 kúrò nínú owó epo pẹtiró
Yínká Àlàbí
Gbajugbaja onisowo epo ni orileede yii ti o tun je ẹni to lowo ju ni ile adulawọ, Aliko Dangote ti ran oludari ile isẹ epo rẹ, Anthony Chiejina pe ko din owo epo petiro naa ku.
Ọgbọn naira ni wọn yọ kuro ninu owo epo naa ni alẹ ọjọ Isẹgun, ọjọ kejila, osu kẹjọ, ọdun yii. Dipo N850 ti wọn n gbe epo kuro ni ileesẹ Dangote, wọn maa gbe bayii ni N820 fun jala epo kan.
Ile isẹ Dangote si se ileri pe awon ko ni dun ọmọ Naijiria ni epo naa, Anthony Chiejina tun ni ile isẹ ifọpo Dangote tun maa bẹrẹ si ni gbe afẹfẹ ti mọto n lo naa jade ni ọpọ yanturu lati ọjọ kẹẹdogun, osu kẹjọ ọdun yii. O ni eyi wa fun irọrun awọn ọmọ orileede yii.
Wọn ni iye jala gaasi ti ko ni din ni ẹgbẹrun mẹrin (4,000 Compressed Natural Gas) lo maa bẹrẹ si ni jade lẹẹkan naa.