Danboskid ní orúko̩ tí òun yípadà ló jé̩ kí òun tètè jáde lórí ètò BBNaija

Danboskid ní orúko̩ tí òun yípadà ló jé̩ kí òun tètè jáde lórí ètò BBNaija

Mary Fágbohùn

Omole BBNaija abala 10 to ti jade ninu ile, Danboskid ti so pe oruko ti oun yipada ninu ile BBNaija House lo je ko soro fun awon ololufe oun lati da oun mo.

E o ranti pe Danboskid ni omole akoko to jade lori eto naa leyin ise meji to gbe ni ile Biggie.

Danboskid, eni ti oruko re gangan n je Daniel Olatunji, je eni odun marundinlogbon lati ipinle Ekiti.

Lasiko to n soro lori eto mohunmaworan Arise TV, 360 Chats, Danboskid ni oun fi oruko kan sile to ba ikanni ayelujara oun mu sugbon awon alakoso ko pe irufe oruko ti won to fi sile.

Gege bi o se so, eyi lo mu ko soro fun awon afenifere ti won n wo eto naa lati da oun mo.

O ni: “Nigba ti mo wo inu ile, mo fun won ni oruko to ba ikanni ayelujara mi mu, sugbon awon alakoso ni won o fe eni to ni oruko ti won ti fi sile. Mo wa yipada si Danboskid, mi o le ba awon ti n se agbateru mi nita soro. Eyi lo mu ko le fun awon ololufe mi lati da mi mo.