Charly Boy sè’kìlo̩ fún àwo̩n olósèlú Naijiria

Charly Boy sè’kìlo̩ fún àwo̩n olósèlú Naijiria

Mary Fágbohùn

Lori oro eto idibo odun 2027, gbajumo olorin, Charly Boy, ti fa awon oloselu leti lati mase dabaa pe won yoo se magomago kan ninu eto idibo gbogboogbo 2027.

Charly Boy se’kilo yi ninu iforo-wani-lenu-wo re pelu Rudolf Okonkwo lori eto 90MinutesAfrica, o ni eto idibo to n bo ohun yoo je akoko to nitumo fun orileede.

Olorin naa ti a mo bii Area Fada (Baba Adugbo), fikun un pe akoko ọrọ fun eto idibo to n bo ni “fowo yi ki o ku”.

“Eto idibo 2027 yoo je akoko to nitumo ni Naijiria. Enikeni to ba seto lati fowo yi ibo ni ko setan lati ku. Fowo yi ki o ku ni.
“Nitori nigba naa, oju wa yoo ti la. O ti n la diedie. Ohun ti a maa ri ni 2026 yoo je ki awon omo Naijiria pinnu boya ko tesiwaju ni tabi ki won mu ki atunse sele ni orileede yi,” o so bee.

Ninu alaye re, o fikun un pe eto idibo ti ko leja-n-bakan ninu ni ona kan soso lati koju isejoba ti ko dara.

“Ona abayo kan si isejoba ti ko dara ni Naijiria le wa nigba ti won ba ka ibo wa nitooto. Nitori naa, ohun to ye ko kan wa bayii ni bi ibo wa se le di kika nitooto ni 2027,” o fikun un.