B’órí se kó Pasuma yọ lọ́wọ́ àwọn agbébọnrìn

B’órí se kó Pasuma yọ lọ́wọ́ àwọn agbébọnrìn 

 

Mary Fágbohùn

 

Wahala ba ilu Ikire to wa nijoba ibile Irewole nipinle Osun lojo Aiku latari ikọlu ti gbajugbaja olorin Fuji, Alhaji Wasiu Alabi Pasuma.

 

Ikọlu naa, eyi ti o waye ni ọsan, wa pẹlu awọn janduku ni afurasi ti wọn sọ pe wọn sọ okuta ti wọn tun yinbọn si awọn ọkọ ayọkẹlẹ, pẹlu Hummer Jeep dudu ati ọkọ nla Hilux funfun kan.

 

Awọn ẹlẹrii ti o wa ni aaye naa sọ pe awọn ọkọ ayọkẹlẹ ni won bajẹ pupo.

 

Amo sa, ko ṣe akiyesi boya eyikeyi ninu awon ọmọ ẹgbẹ Pasuma farapa ninu iṣẹlẹ naa.

 

Fonran to ti lo kaakiri lorí ẹ̀rọ ayélujára safihàn laasigbo kan ti àwọn èèyàn ń pariwo ni abele àti ohùn kan ní èdè Gẹ̀ẹ́sì tí wọ́n ń ké ní “Kasala don bust for Ikire (Wahala ti sele ni Ikire). Wọ́n kọlù wá, wọ́n gbé ìbọn, won yinbọn lu wa, sugbon Ọlọ́run wa.”

 

Igbiyanju awọn oniroyin lati de ọdọ akọrin Fuji tabi ẹgbẹ iṣakoso rẹ fun awọn asọye ko yọri si rere titi di asiko ti a n gbe iroyin yii silẹ.

 

Awọn olugbe agbegbe naa ṣalaye iyalẹnu lori iṣẹlẹ naa, eyi ti o da awọn iṣẹ duro ni agbegbe naa ti o si fa ijaaya igba diẹ laarin awọn ti won n kọja ati awọn oniṣowo.

 

Pasuma ti wa ni ipinle naa fun ere kan, bo tilẹ jẹ pe alaye gangan lori abẹwo rẹ ko ti fidi mulẹ.

 

Titi di asiko iroyin yii, ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ọṣun ko tii fi ọrọ kan sita nipa ikọlu naa tabi boya wọn ti mu wọn.