Tinubu-Shettima: Ọmọ ẹni kìí sè’dí bẹ̀bẹ̀rẹ̀…

Tinubu ati Shettima

Lasun Alagbe

Ohun mẹ́fà tó le má jẹ́ kí Tinubu ní wàhálà ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn ní’lẹ̀ Yoruba…

Leyin bii osu kan ti oludije Aaare ninu egbe All Progressives Congress, Asiwaju Bola Tinubu, ti fa Gomina Ipinle Bornu tele, Alhaji Kashim Shettima, sile gege bii olubadupo re, awuyewuye ti ipinnu naa da sile ko tii tan nile.

Awon elesin igbagbo kan n fariga pe, la, awon ko le gba ki Aare je Musulumi, ki igbakeji re naa tun je elesin Islam. Eyi ni eredi awuyewuye Muslim-Muslim ticket ti awon kan n ko gege bi orin.

Iberu won da leri eyameya esin ni ile Naijiria, to je pe awon olori kan n da esin po mo iselu.

Bakan naa, won wo o pe wahala awon alakatakiti terrorists ti won n kolu awon elesin Igbagbo, paapaa l’Oke Oya, ti won si tun da oro ni ilu Owo, ni Ipinle Ondo, laipe yii, ye ki o fu enikeni lara.

Nipa bee, won ni awon n fe ki Tinubu tun ero naa ro.

Ni awon abala orile ede Naijiria miran, awon kan naa n pariwo lori oro yii.

Ni Oke Oya, awon Kirisiteeni kan ni egbe APC ti yi awon mere.

Won ni Tinubu fi owo ola gba awon loju.

Lara awon eni to tenu mo oro naa ju ni Alagba Babachir Lawal, to figba kan je Akowe fun Ijoba Apapo fun Buhari.

Ojoojumo lo n figbe ta pe Tinubu ko se e daadaa bi o se fa Shettima bodi naa.

Bi a ko ba gbagbe, Babachir Lawal ni won yo bi eni yo jiga nigba kan lori esun pe o na owo to le ni ogorun meji milioonu lati ge papa.

Bakan naa ni awon  alagba ijo kan ni Oke Oya n se arokan tii fa ekun asun-un-da lori bi won ko se fi elesin Igbagbo se igbakeji Tinubu.

Ni apa ila oorun naa, iyen laarin awon Igbo, awon kan naa n se awuyewuye.

Won ni kii se ohun to dara fun ajosepo ati ijoba tiwantiwa ki esin kan maa se bi eni je gaba lori omiran.

 A ranti bi ogunna gbongbo ni Niger Delta, Oloye Edwin Clark, naa tuto soke, to foju gba a lori oro yii bakan naa.

Tinubu

 Sugbon sa o, ohun to koju si eni kan, eyin lo ko si elomiran.

A ri opo awon elesin Igbagbo ni Oke Oya ati Ila Oorun naa ti won ni ko si ohun to buru ninu bi Tinubu ati Shettima se n soju egbe oselu naa.

Won ni ko si ohun toju ko ri ri, tori o sele laye MKO Abiola pelu Basir Tofa, laye June 12 ti gbogbo aye dibo fun Abiola.

Bakan naa, won ni ibi ti irepo gidi ati oro itesiwaju ba ti je awon eniyan lokan, oro esin ko to ohun ti won maa n gbe leri bee.

Leyin eleyii, Tinubu ati egbe APC naa n se alaye pe oro tikeeti Musulumi  pelu Musulumi awon, oro afojudi ko, oro afojusun oselu ni.

Won ni awon ni lati wo ta lo le mu ibo wa ju ni Oke Oya, nibi ti ibo ti maa n po bii baba Esua,  ni.

Sugbon ka ma fi oro sile soro, ohun ti OSUMARE n so pato ninu akosile yii da leri ironu erongba awon Kirisiteeni ni ile Yoruba lori oro Tinubu pelu Shettima naa.

Ni ile Yoruba, kii saaba si oro eleyameya lori esin.

Ninu ile kan soso, a le ri Musulumi, ka ri Kirisiteeni, ka ri Onifa, ki Onisango paapaa ma ba faaji lo – ko ma si ija pelu ita.

O se maa wa je pe tikeeti APC naa yoo fa awiyewuye nibe?

Lona kinni, awon awoye n so pe Tinubu ti opo eniyan mo kii se eni to maa n gbe esin leri tabi to maa n di esin sinu lati da awon eni kan loro.

Koda, kii se eyameya.

Won tun ranti pe iyawo re, iyen Senato Oluremi Tinubu, elesin Igbagbo ni. To si je pe eekan kan pataki lo je ni ijo Ridiimu.

Nje iru eni bee wa le fi eje sinu ko tu ito funfun jade si awon omoleyin Jesu Kristi bi?

Bi awon omo Naijiria se n ro oro naa lo siwaju ati seyin lo mu ki OSUMARE, to je magasinini IROYIN OWURO, o maa wo sakun ibo ni awon Kirisiteeni Yoruba yoo dibo si ni 2023.

Leyin opo eniyan ti ko ri aburu kankan ninu ohun ti Tinubu se, awon Kirisiteeni Yoruba kan ti won lawon lodi si Tinubu pelu Shettima nko?

Se won a wa fi Tinubu omo won sile, won yoo dibo fun omo ibomiran ni?

Eyi le ma je lori oro eleye meya, sugbon gbogbo wa la mo ohun ti Yoruba ni lokan nigba ti won so pe tiwa n tiwa, tekisa ni taatan.

Bee naani naani, naani, ohun a nil aa naani: omo agbade naani oko, omo asegita n naani eepo igi.

Ko tan sibe o, Yooba bo won ni omo eni ko le sedi bebere, ka fi ileke si idi omo elomiran.

Eyi mu ki OSUMARE maa wo o pe bawo ni 2023 yoo se lo.

A si ni igbagbo pe lara awon ti won ni awon n binu yii, ibinu won ko le je abidele, debi ki won ma dibo fun Tinubu.

Tinubu ati Ooni ti Ifle-Ife, Oba Adeyeye Ogunwusi

Itumo aidibo fun Tinubu le tumo si ki won dibo fun egbe Peoples Democratic Party, iyen Alhaji Atiku Abubakar to je asoju fun egbe PDP.

Ti won ba se bayii, se won fe ki ijoba tun pada si Oke Oya ni?

Eni ti awon eniyan tun n ran monu ni Alagba Peter Obi ti egbe Labour Party.

Awon kan ni oro bi awon se n pariwo re kii se lori  oro esin.

Won ni erongba re ati oye to ni lori iselu onidagbasoke ni, bi o tile je pe awon kan naa n so pe eni ti yoo daso fun ni, torun re laa wo.

Won n beere pe nigba to se ijoba gege bii gomina ni odun mejo ni Anambra, awon ko ri aseyori kan pato to se.

Boya oro ojo miran ni eyi, ati pe o le je pe ota eni kii pa odu oya ni.

Ni pataki, awon awoye kan naa ko gbabgbe pe, bi a fe, bi a ko, bi a wi d’oni, d’ola, eya Peter Obi naa ko yipada. Omo Igbo kuku ni oun naa.

Se Tinubu omo eni a wa se idi bebere ka fi ileke si ibadi omo  elomiran ni? Iyen gege bi awon awoye naa se n wo o.

Ni kukuru, o jo pe oro tikeeti Musulumi ko le fa wahala ju fun Tinubu ni ile Yoruba.

Leyin pe o je eni ti ko gbe esin leju, ti yawo re si je Kirisiteeni, opo eniyan naa lo je kirisiteeni ti won si je omo egbe APC.

Iru won setan lati dibo fun Asiwaju lojo kojo.

Bakan naa, a ni awon eniyan nla nla ti enu won si mule laarin awon Kirisiteeni ile Yoruba, awon ogunna gbongbo bii Igbakeji Aaare, Ojogbon Yemi Osinbajo.

Bo tile je pe tirela gba aarin oun at Tinubu koja lasiko ibo ebele APC, won ti jo pada sinu egbe.

Iru won yoo le petu si awon eniyan won ninu Oluwa ninu.

Bakan naa, awon Gomina Ipine Yoruba merin kan ti egbe APC ti n se ijoba ni won je elesin Kirisiteeni.

Awon naa ni Babajide Sanwo-Olu ti Ipinle Eko, Dapo Abiodun ti Ogun, Rotimi Akeredolu ti Ipinle Ondo ati Kayode Fayemi ti Ipinle Ekiti.

Awon mereerin yii yoo sise takuntakun lati  ri i pe opo elesin Igbagbo dibo won fun Tinubu.

Ko tan sibe o, a gbo pe awon ipade alabeele ati bonkele kan ti n lo laarin awon eniyan Tunubu ati awon olori elesin Kirisiteeni ni ile Yoruba.

Se awon oloselu mo bi awon se maa n se nnkan tiwon.

Nnkan kan to tun se pataki ti ko mo eya tabi esin ni oro owo.

Afojuwo awon awoye kan ni pe oselu dibo-koo-sebe lo n lo lowo ni Naijiria, ti a ko ba ni tan ara wa.

Ti ibo ba de, awon eniyan kan ko ni ranti boya esin kan ni oludije kan n sin, ti won ba ti fi nnkan le won lowo.

OSUMARE ko le so oro eleyii ni asoju, tori a ko fi ara mo ki a ma  fi owo ra ibo; sugbon opo eniyan naa lo mo bo se n lo.

Lati fi enu oro yii Jonna, awon koko oro bii mewaa ti a se ro pe Tinubu o ni ni wahala lori Muslim-Muslim ticket ni ile Yoruba niwonyi:

–         O ni afojudi ko lo mu ohun yan Shettima laayo, afojusun oselu ni.

–         Tinubu funra re kii se eleya-meya tabi elesin-mesin.

–         Tinubu gan-an, Kirisiteeni ni iyawo re.

–         O je eni to ti se fun Alara, Ajero ati Owarangun Aga teletele – ki iyen maa je owe.

–         Laarin awon Yoruba, oro esin kii fa wahala oselu.

–         Owe omo eni ko ni se idi bebere, ka fi ileke si idi omo elomiran yoo mu ki opo tun ero pa.

 

–         Laarin egbe APC, opo Kirisiteeni wa ti won yo dibo fun Tinubu, ti won yoo si tun so fun egbe won miran ki won se bee.

–         Awon gomina Yoruba merin lo je elesin Igbagbo funra won: Gomina Babajide Sanwo-Olu, Gomina Dapo Abiodun, Gomina Rotimi Akeredolu ati Gomina Kayode Fayemi.

–         A gbo pe APC ti n se ipade bonkele pelu awon olori esin Igbagbo kan.

–         Bakan naa, eni to ba se owo kuduro si awon elomiran ni won yoo dibo fun – lai naani esin yowu to na n sin.

Ni akotan, arojinle yii kii se lati se ipolongo ibo fun enikeni.

Akawe, arojinle, ifojusun lori bi nnkan se le lo nile Yoruba ni 2023 ni.

Ki Olorun so emi gbogbo wa ju igba naa lo.

 LATI INU MAGASIINI ‘OSUMARE YORUBA’

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here