“Bola Tinubu gbé owó ńlá fún èmi àti Adebayo Faleti

“Bola Tinubu gbé owó ńlá fún èmi àti Adebayo Faleti

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé wọ́n ní aríṣe ni aríkà, bẹ́ẹ̀ aríkà ni baba ìrègún. àṣamọ̀ yẹn ló bí àkọlé ìròyìn òkè yìí.
Gọ̀baẹ́júmọ̀ òṣèré tíátà ni èdè Yorùbá, Olóyè Lere Paimo tí ọ̀pọ̀ èèyàn mọ̀ sí Ẹ̀dá Oníléọlá, tí ṣàlàyé ọ̀pọ̀ nnkan nípa ìgbésí ayé rẹ.

Lere Paimo, lásìkò tó ń kopa ninu ifọrọwerọ pẹlu Jeff Owolewa lórí ayélujára sọ̀rọ̀ nípa àwọn sinimá tó ti kopa ninu rẹ àti ibasepọ rẹ pẹlu awọn èèkàn ìlú ni awujọ bíi Oloye Olusegun Obasanjo àti Aare Bola Tinubu.

Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí bó ṣe ni imisi láti kọ ìtàn eré tíátà tó sọ di gbajumọ, eyiun ere Ogbori Elemoso, Lere Paimo ni òun ká ìwé ìtàn kan nípa idasilẹ ìlú Ogbomoso èyí tí Ọjọgbọn N.D Oyerinde kọ ni.

Ẹda Onileola ni ère Saworo Idẹ tún jẹ́ ere sinimá kan tó fún òun ní òkìkí lásìkò tí Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu wá nípò gomina nipinlẹ Eko.

Mo wá lọ kí Bola Tinubu ni Èkó, wọn fún mi jí owo, bákan náà, wọn ní kí n fún alàgbà Adebayo Faleti ni owo pẹlu.

Bi mo ṣe gbé owó náà fún Faleti, kò mọ ohun tó le se mọ, ó sá yanu silẹ ni torí ṣáájú ọjọ́ náà, ní kó rí owó irinṣẹ oko tó yá láti ṣiṣẹ nínú oko rẹ san, táwọn onitoun si ko àwọn irinṣẹ naa lọ.

Owo ti mo fún wọn náà, wọn kò rí irú rẹ rí.”

Kódà, Eda Onileola tún mẹ́nubà àwọn àmì ẹyẹ tó tí gba bíi àmì ẹyẹ osere tó dantọ julọ