Bishop jẹ́rìí sí ìtúsílẹ̀ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Niger
Yínká Àlàbí
Bishop ti Kontagora Diocese ati Proprietor ti St. Mary’s Private Catholic Primary ati Secondary, Papiri, ipinle Niger, Most Rev. Bulus Yohanna, ti jẹrii si itusilẹ awọn akẹkọọ ile-iwe naa.
Dan Atori to jẹ olubani-damọran fun Bishop lo salaye yii fun oniroyin.
O salaye pe gomina ipinlẹ Niger, Umaru Bago ni lati ri awọn akẹkọọ naa ni ilu Minna ni oni ọjọ kejilelogun, osu kejila ọdun yii ki wọn to gba ọdọ awọn obi wọn lọ.









