“Bí wọn kò bá ṣe ètùtù ikú Awujalẹ Adetona, yóò dààmú Ìjẹ̀bú-Òde”

“Bí wọn kò bá ṣe ètùtù ikú Awujalẹ Adetona, yóò dààmú Ìjẹ̀bú-Òde”

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àwọn àgbà sọ pé bí ọ̀rọ̀ ńlá kò bá tí ì tán èèyàn,ńlá kò ní-ín sinmi àròyé.
Àgbà oyè kan ni ilu ijebu Ode, Razak Adeneye Oshimodi, tii se Ọlọ́wá Ìbẹ̀rù ti Ìjẹ̀bú-Òde àti Abọrẹ̀ Akile Ìjẹ̀bú tí sọ̀rọ̀ lórí ìṣẹ̀ṣe.

Ọlọ́wá, tii ṣe àgbà òye kẹta sí Awujalẹ lẹ́yìn Olisa, ṣàlàyé pé bí wọ́n ko bá ṣe orò lẹ́yìn ikú Awujalẹ to papoda laipẹ yìí, Ọba Sikiru Kayode Adetona, ìgbésẹ̀ náà le e lẹ́yìn, tí yóò sì dààmú ìlú Ijebu Ode.

Agba Oye Oshimodi, woye ọ̀rọ̀ náà nínú ifọrọwerọ to bá ileeṣẹ ìròyìn Punch se, èyí tí fídíò rẹ ń jà lórí ayélujára.

Àmọ́ ó wá gbáà ní àdúrà pé Ọlọ́run kò ní jẹ́ kí ìdààmú bá ìlú Ìjẹ̀bú Òde lórí ọ̀rọ̀ to ń jà nílẹ̀ náà.

Ọlọ́wá Ibẹru ni Ọba to bá sọ pé ọba lé ma ṣe ìṣẹ̀ṣe, torí kò ṣe ìṣẹ̀ṣe kò tó dé orí ìtẹ́, kò mọ òun tó ń sọ ní.

“Adé tó wà lórí rẹ̀, ta ló ni í? Ìlẹ̀kẹ̀ ṣẹ́ṣẹ́ ẹfun tó wà lọrun rẹ̀, ta ló ni í? Ó ní Òrìsà to ni adé yẹn, òrìṣà ló ni í.

Wọ́n máa lé ìtẹ́ fún ọba, kó tó le jókòó sórí ìtẹ́ náà. Ọba tí wọn bá sì lé ìtẹ́ fún, kìí ṣe Mùsùlùmí ni yóò wá ka Tírà níbẹ̀.

Mo ti sọ pé tí wọn kò bá ṣe ètùtù fún ikú ọba Sikiru Adetona, ó máa dààmú Ìjẹ̀bú-Òde torí ọba kan kò gbọ́dọ̀ da ní àṣà pé òun kò bá oníṣẹ̀ṣe jẹ.

Gbogbo ohun tó bá bá ní ààfin pátápátá, nǹkan ìṣẹ̀ṣe ni torí kò sí ààfin tí ẹ máa dé, tí ẹ kò ní bá nǹkan ìṣẹ̀ṣe níbẹ̀.

Ọba tí ó bá sọ bẹẹ, igbẹyin wọn kì í dára, pàápàá ni ọdọ wa nibi, ní Ìjẹ̀bú Òde.

Àwa oníṣẹ̀ṣe ni a máa ṣètò bí gbogbo nnkan ṣe máa tuba tusẹ fun Ọba, torí kí ìlú má bàa dàrú, ní àwa oníṣẹ̀ṣe ṣe yẹba.

Olisa lo bẹ oníṣẹ̀ṣe pé kí wọ́n má jẹ ki ìlú dàrú lórí tòun, bí wọn ṣe ń pariwo pé kí oníṣẹ̀ṣe máa lọ lọ́jọ́ ìsìnkú yẹn, bí wọ́n bá yán ìgbálẹ̀ sí wọn, onítọ̀hún yóò ti mọ ibi tí ara òun kù sí.

Ní ọdún 1960, odindi ìlú kan tí irufẹ ìṣẹ̀lẹ̀ yìí tí wáyé, ṣe ló tú, n kò ní dárúkọ ìlú náà.