O ti se itore aanu bii bilionu mewaa naira laarin odun meji
Ipa to n ko han ju ti awon minisita miran lo
Lopo igba, awon amoye oselu maa n se awuyewuye lori ipo iyawo Aare tabi Iyawo Gomina, eyi ti a mo si First Lady, ninu ijoba tiwa-n-tiwa. Opo eniyan lo gba pe iwe ofin, iyen Constitution, ko fi aaye sile fun oofisi ‘Obinrin Akoko’. Nipa idi eyi, won ni ko ba ofin mu bi awon iyawo to maa n ya gele yaya naa se maa n se bi eni a dibo yan.
Sugbon awon eniyan kan naa gba pe iru ero bee dun un wi lenu ni, o nira lati mu u se. Won ni bi Aare tabi Gomina kan fe, bo ko, iyawo re naa yoo fe ki araye mo pe oun naa wa nibe. Ko ni fe ki won je oun maye.
Ti a ko ba gbagbe, lati aye ijoba Ogagun Ibrahim Babangida ni ipo ‘First Lady’ ti di gbajugbaja, nigba ti iyawo re, Oloogbe Maryam Babangida, se agbateru eto igbesi aye to derun fun awon obinrin igberiko — Better Life for Rural Women. Iyawo Abacha, Iyaafin Maryam Abacha, naa se tie lasiko ti oko re.
Nigba to si di aye ipadabo ijoba alagbada ni 1999, bi Oloye Olusegun Obasanjo se kanju ko to, iyawo re, Oloogbe Stella Obasanjo, naa lo ipo Obinrin Akoko.
Laye Dokita Goodluck Jonathan naa, aya re, Iyaafin Patience Jonathan, dan mewaa wo, debi wi pe enu re ni awon eniyan ti ja ‘Dis is God o’ gba.
Nigba ti Ogagun Feyinti Muhammadu Buhari naa si gori aleefa, ti oun naa fe se bii kogberegbe, bo fe, bo ko, iyawo re, Aisha Buhari, naa ko je ki won je oun maye, to si se awon eto kan.
Sugbon sa o, lopo igba, awon iyawo olori joba miiran maa n da wahala si baale won lorun.
Won le maa be gaugau, ti won si maa n ko owo je bi ile ba da.
Ti a ba wa wo ijoba Asiwaju Bola Tinubu, o jo pe rere ni fere iyawo re, Senito Oluremi Tinubu, n fon.
Lati igba ti won tide ijoba ni 2023 lo ti fun gbaja re monu, to si n seto iranlowo fun awon alaini tabi awon to wa ninu isoro.
Remi Tinubu, labe asia ajo Renewed Hope Initiative re, n lo kaakiri Naijiria, to si je pe awon to ba gba a lalejo maa n ri ipa gidi to n ko.
O n soro to lopolo gbe ijoba oko re; o n se alaye eredi awon eto ijoba to je ki nnkan won gogo. Bee, o si n korin ireti ayo si awon eniyan leti.
Remi Tinubu n se eyi debi wi pe o n se ju awon minisita kan lo.
Loooto, awon minisita kan wa ni ijoba Tinubu to je pe bii olundu ni won.
A ko gbo ki won soro iwuri gidi kan; a ko si ri nnkan gbogi ti won n se.
Sugbon ni ti Remi Tinubu, ipa to n ko han debi wi pe awon eniyan kan ti n beere pe ibo lo ti n ri owo to n na — se elenu mji ni omo araye, ati pe afifila pa efon, ojo kan lo maa n niyi mo.
Ni pataki, iranlowo owo ti ajo Renewed Hope Initiative ti se fun awon eniyan, ati ajo gbogbo ti to bilionu mewaa naira.
Lara awon ti won ti je anfaani owo naa ni awon obinrin, awon akekoo, awon omo orukan, iyawo awon ologun to ti ku, awon arugbo ati awon ile iwe kan.
Lara awon eto iranlowo naa, a ranti bi iyawo Tinubu se fun awon ebi metadinlogota (57) ni egberun lona oke mejila aabo N250,000 eni kookan nigba ti agbara ojo se won lose ni ilu Abuja.
Gbogbo owo naa le ni milionu merinla lodun naa.in
Ajo Renewed Hope tun fun awon ti alakatakiti da si wahala ni Maiduguri ni ilaji bilionu naira kan, iyen N500m.
O fun awon iyawo awon jagunjagun to ti ku ni owo to le ni irinwo milionu (N427.75m), nibi ti ebi kookan ti gba N250,000.
Ni odun 2024, owo to din die ni bilionu meji naira (N1.9bn) ni won la sile lati na fun iranlowo awon agbalagba kaakiri Naijiria.
Ajo naa fun awon ebi ti rogbodiyan ko si wahala ni Ipinle Plateau ni eedegbeta milionu naira (N500m).
Bee awon eniyan ko gbagbe pe Senito Remi Tinubu fun ile iwe Obafemi Awolowo University ni bilionu kan naira, to si bun Joseph Ayo Babalola University ni aadota milionu naira (N50m) fun iranlowo awon obinrin akekogboye obinrin to se daadaa.
Lori ibi ti awon owo kabitikabiti yii ti n jade, iyawo Aare ni awon oluranlowo kan, alaanu ara Samaria, lo wa leyin Rened Hope Initiative.
O ni lara won ni awon ileese kan ati awon ajo miran.
Bi o tile je pe o so wi pe opo awon atinileyin bee ko fe ki won pariwo oruko awon, o ni lara won ni ile ise Bua, eyi to maa n se simenti.
Ni pataki, IROYIN OWURO woye pe o jo pe Remi Tinubu n ko ipa pataki ninu ijoba baale re.
O ti wa da bii eleyinju aanu, paapaa nigba ti gbpogbo nnkan gbenu soke.
O gbaju mo ise Renewed Hope to n se naa, to si n se e bi eni pe won yan an si ipo ni.
Ohun to tun se pataki ninu akiyesi awon onwoye ni pe ko maa ko auyewuye ba oko re, bi awon akegbe re kan tele ti se.