Bí àwo̩n òsìsé̩ NFF se pa ìran bó̩ò̩lù gbígbá mi – Olorin, Crayon
Mary Fágbohùn
Gbajumo olorin, Charles Chibuezechukwu, ti a mo si Crayon, ti seranti bi awon osise ajo apapo boolu Naijiria (Nigeria Football Federation, NFF), se ge iran re bii agbaboolu kuru leyin ti won yan awon omo egbe agbaboolu orile ede lati awon idile ti o lowo.
Olorin ‘Trench To Triumph’ naa so pe won yan oun bii okan lara awon odo agbaboolu fun orile ede ni 2015 sugbon ti awon osise ti won kun iwa jegudujera ja oun sile.
O safihan eyi ninu iforo-wani-lenu-wo to se laipe pelu ile ise asoromagbesi Cool FM Naijiria ni Eko.
O so pe isele naa lowo si ibanuje okan ti oun koju ni odun 2015.
Crayon wi pe, “Mo di eni to ni ibanuje okan ni 2015 nitori pe mi o le lo si fasiti. Gbogbo awon ore mi wa ni ile iwe. Ni igba naa mo si sunmo awon ore mi. Emi ni mo kere ju laarin awon ore mi. Ara mi maa n ya gaga ni igbakugba ti won ba wa ni ayika mi. Gbogbo won ri iwe igbawole si fasiti ni Ghana, Benin, abbl. O wa ku emi nikan ni adugbo.
“O sun mi gidi. Mi o ni nnkan ti mo le se, ko si ibi ti mo le lo. Ise agbaboolu ni igba naa ko se deede fun mi. Mo maa n gba boolu tele. Mo je agbaboolu gidi. Won n pe mi ni ‘Coutinho’ ni adugbo mi. E mo Coutinho to n gba bowolu fun Liverpool?
“Mo gbiyanju lati mu boolu gbigba bii ise sugbon ko sise fun mi nitori Naijiria kun fun iwa jegudujera. Opolopo iwa ibaje lo wa. Mi o fe daruko nitori o le dun awon eniyan kan. Oruko nla ni; awon agba osise [boolu].
“Ni igba naa mo lo fun idanwo kan ni Surulere [papa isere orile ede], won [awon osise NFF] mu mi leyin eyi ti won ja mi sile ki won le mu elomiran nitori eni naa lowo o si mo eniyan. Nitori naa, ni igba naa, mo ni ijakule. mo pada sile pelu ibanuje okan.”