Báyìí ni Boko Haram ṣe ń lo Tiktok fún ìpolongo ní Naijiria
Fẹ́mi Akínṣọlá
Ikọ̀ agbébọn Boko Haram àti ISWAP, tó ń da gbogbo ìgboro ní apá àríwá rú fún ìgbà pípẹ́, ni wọ́n ṣiṣẹ́ láti tún tàn ká gbogbo orilẹ̀ -èdè Nàìjíríà pẹ̀lú àtẹ̀jíṣẹ́ tí wọ́n ń fi ránṣẹ́ sí àwọn èèyàn pé kí wọ́n darapọ̀ mọ.
O le ni ọgọrun un eeyan ti ikọ agbebọn yii ṣekupa ninu ikọlu to waye ninu oṣu Kẹrin, gẹgẹ bii gomina ipinlẹ Borno ṣe sọ, to si jẹ pe ikọlu naa lo ṣekupa eeyan to pọ ju lati ọdun 2009, to si jẹ ọpọ igba ni wọn ti kọlu awọn ipinlẹ mii lorilẹede Naijiria.
Awọn agbebọn ọhun tun ṣafihan awọn ibọn lori opo ayelujara Tiktok pẹlu awọn ohun ija oloro miiran ati owo ninu oṣu kẹrin.
“O bẹrẹ pẹlu awọn agbebọn.” Bulama Bukarti, igbakeji aarẹ ẹgbẹ Bridge ni Texas ṣalaye loju opo ayelujara X.
“Ni bayii awọn agbebọn Boko Haram ti n ṣe fọnran sita loju opo X – ipolongo wọn, ti wọn si n dunkoko mọ awọn to ba bu ẹnu atẹlu wọn.”
Bulama ni, ọmọ ikọ agbebọn Boko Haram ti fi igba kan dunkoko mọ oun ninu fọnran kan ti wọn ti yọ kuro nitori o bu ẹnu atẹlu ise wọn.
Bo ti lẹ jẹ pe ọpọ oju opo to n ṣe igbelarugẹ ohun ti ẹgbẹ naa n ṣe ti palẹmọ, awọn fọnran ti wọn n gbe sita n tako igbinyanju lati mu wọn.
Agbẹnusọ Tiktok ni, o nira pupọ lati ri awọn oju opo ti awọn agbebọn yii fi n ṣe fọnran sita nitori wọn yọ wọn kuro lẹsẹkẹsẹ.
Oju opo mọkandinlogun ti ileeṣẹ AFP ṣe iwadii le lori ṣafihan awọn eeyan kan ti wọn mura bi alfa, ti awọn miiran si da nnkan boju wọn, ti wọn si n sọrọ tako ijọba.
Awọn oju opo miiran n ṣafihan awọn fọnran olori Boko Haram tẹlẹ, Mohammed Yusuf ati Isah Garo Assalafy, ẹni ti wọn fofin de pe ko gbudọ ṣe waasu ita gbangba mọ nipinlẹ Niger nitori o n lo awọn ikorira, to si n tako ọlaju.
O kere, ikọ agbebọn Boko Haram ti ṣekupa o le ni ẹgbẹrun lọna ogoji eeyan, ti wọn si tun sọ ọpo eeyan di abarapa.
Saddiku Muhammad, ẹni to ti fi igba kan jẹ ọmọ ẹgbẹ Boko Haram sọ fun AFP pe awọn agbebọn Boko Haram ti n lo oju opo Tiktok nitori awọn oṣiṣẹ Ologun n ṣawari wọn loju opo Telegram.
Wọn ti ri pe ọpọ awọn ọdọ lo wa loju opo Tiktok bayii.
“Wọn ri pe ọdọ pọ nibẹ, wọn dẹ nilo lati lo nnkan ti awọn ọdọ nifẹ si,” Muhammed sọ.
“O fẹ da bi pe wọn n bori. Ohun to wa niwaju wọn bayii ni lati ri awọn ọdọ kojọ..”
Awọn amoye sọ fun AFP pe bi awọn agbebọn ṣe n lo Tiktok lo jẹ ohun ibẹru fun ijọba.
Malik Samuel, amoye nipa eto aabo ni Boko Haram n lo opo yìí láti gbinyanju tan awọn ọdọ ki wọn darapọ mọ wọn pẹlu ipolongo wọn.
“Wọn n mọmọ fi oju wọn han sita lati sọ pe ẹru ko ba wọn rara ati pe lati fidi rẹ mulẹ pe eeyan ni awọn naa,” Samuel ṣalaye.
O ni ISWAP fi ẹbun wọn lori fọnran ṣiṣe ju ti Boko Haram lori ayelujara.
Ẹwẹ, Tiktok ti n ṣiṣẹ pọ pẹlu ileeṣẹ kan lorilẹede Gẹẹsi, “Tech Against Terrorism” lati pese ọna lati da awọn agbebọn yii mọ lori ayelujara.