Bánkì àgbà Nàìjíríà taari owó yanturu sáwọn ilé ìfowópamọ́, pawọ́n láṣẹ iṣẹ́ òpin ọ̀sẹ̀
Fẹ́mi Akínṣọlá
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Bánkì àgbà ilẹ̀ yìí ti gbà sílé ẹjọ́ lẹ́nu pé kí wọ́n má a ná owó Orílẹ̀ yìí tẹ́lẹ̀ àti tuntun di Oṣù kejìlá ọdún yìí, síbẹ̀, igbe kò sí káàsì náà ló sì lógboro pá títí di àsìkò yìí tí àwọn ọmọ Orílẹ̀ yìí sì n kérora lórí owó o wọn to
hà, ṣùgbọ́nlé níbáyìí, ilé ìfowópamọ́ àgbà ilẹ̀ Nàìjíríà, CBN ti kéde pé àwọn ti fi ọ̀pọ̀ owó yanturu ránṣẹ́ sí àwọn ilé ìfowópamọ́ káàkiri orílẹ̀ èdè láti le ko jáde fún àwọn ènìyàn.
CBN ní ìgbésẹ̀ yìí wáyé láti le mú àdínkù bá ìṣòro tí àwọn ènìyàn ń kojú láti rí owó ná.
Bákan náà ni wọ́n tún darí àwọn ilé ìfowópamọ́ náà láti máa ṣiṣẹ́ ní àwọn òpin ọ̀sẹ̀, ìyẹn ní ọjọ́ Àbámẹ́ta àti ọjọ́ Àìkú títí tí gbogbo àwọn ìṣòro àìsí owó níta yìí máa fi kásẹ̀ nílẹ̀.
Adarí ẹ̀ka ìbánisọ̀rọ̀ CBN, Dókítà Isa Abdulmumin tó fi ìkéde náà léde ní Abuja lọ́jọ́ Ẹtì ní ọ̀bítíbitì owó ni CBN ti fi ṣọwọ́ sí àwọn ilé ìfowópamọ́ láti pín fún àwọn oníbàárà wọn.
Abdulmumin fi kún un pé CBN tún ti pàṣẹ fún àwọn ilé ìfowópamọ́ yìí láti kó owó sínú akoto ATM gbogbo, kí àwọn ènìyàn le máa rí owó gbà jáde nínú rẹ̀.
Ó ṣàlàyé pé gómìnà CBN, Godwin Emefiele máa ríi dájú pé àwọn ṣe àbẹ̀wò sí àwọn ilé ìfowópamọ́ yìí láti mọ bóyá wọ́n tẹ̀lé àṣẹ yìí àti pé Emefiele fúnra rẹ̀ ni yóò ṣaájú ikọ̀ tí yóó máa ṣe àbẹ̀wò yìí.
Ó tún pàrọwà sáwọn ọmọ Nàìjíríà láti túbọ̀ lékún nínú sùúrù wọn àti pé gbogbo ìṣòro àti ìpèníjà tí wọ́n ń là kọjá lórí ọ̀rọ̀ owó Náírà yìí ni yóó di ohun ìgbàgbé láìpẹ́.
Ẹ ó rántí pé ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ Nàìjíríà, NLC ti ṣaájú kéde pé àwọn yóó ṣe ìwọ́de lọ sí gbogbo ẹ̀ka ilé ìfowópamọ́ CBN tí CBN bá kọ̀ láti wá ojútùú sí ìṣòro ọ̀wọ́n gógó owó náírà.