Baba Mohbad sọ̀rọ̀ lórí fídíò tí Naira Marley ṣe

Baba Mohbad sọ̀rọ̀ lórí fídíò tí Naira Marley ṣe

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣe wọ́n ní ọrọ pẹlú àlàyé,
gbajúmọ̀ akọrin tàkasúfèé nnì, Azeez Fashola, tí ọ̀pọ̀ èèyàn mọ̀ sí Naira Marley, ti ṣàlàyé pé àpò àsùnwọ̀n owó ni banki, tó jẹ́ ní ìyá ìyàwó Mohbad, ní olóògbé náà fi ń kọkọ gba owó isẹ rẹ lọwọ òun.

Naira Marley tun sísọ lójú ọrọ yii nínú fídíò kan tó ṣe sórí ayélujára èyí tó fi ń wẹ ara rẹ mọ nípa ikú Ilerioluwa Aloba, tí ọ̀pọ̀ èèyàn mọ̀ sí Mohbad, tó di olóògbé lọ́dún méjì sẹ́yìn.

Naira Marley ni “Mohbad sọ fún mi pé òun ni òun ni àpò àsùnwọ̀n owó náà àmọ́ àṣírí tú nígbà tó yá pé akanti náà kii ṣe tí Mohbad.

A ṣàwárí rẹ pé ìyá Wunmi, tii ṣe ìyàwó Mohbad lo ni akanti tí a ń sanwó si náà, mo sì yari pé ń ko ni sanwó sìnu àpò àsùnwọ̀n owó náà mọ.”

Naira Marley tẹsiwaju pe oun sọ fún Mohbad pe ko lọ sí akanti tiẹ̀ nílé ifowopamọ, inú rẹ sì ni òun yóò máa san owó orin tó bá kọ lábẹ́ ileeṣẹ òun sì.
Ní báyìí, Joseph Aloba, ẹni ti ọpọ eeyan mọ si Baba Mohbad, ti sọrọ sita lori fídíò tí Naira Marley gbe síta, lati ti wẹ ara mọ lori iku Mohbad.

Baba Mohbad, lásìkò tó ń bá akọ̀ròyìn sọrọ, ní Naira Marley ti ṣàlàyé fún òun ṣáájú lori apo asunwọn owó ni banki, ti Mohbad fi n gba owo to ajẹmọnu rẹ náà.

O tẹsiwaju pe ọpọ ohun ti Naira Marley sọ sita lo jẹ pe oun ti sọ sita ṣaaju lasiko ti Mohbad di oloogbe lọdun 2023.