Bàbá Ìjè̩s̩à sì wà l’ó̩gbà ẹ̀wọ̀n

Bàbá Ìjè̩s̩à sì wà l’ó̩gbà ẹ̀wọ̀n

Mary Fágbohùn

Ni bí ọjọ́ die sẹ́yìn ni ìròyìn jade lórí ayélujára nípa gbajúmọ̀ òṣèré tíátà n nì, Olanrewaju Omiyinka James tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Baba Ijes̩a.

Ìròyìn tó ń lọ ni pé òṣèré náà ti kúrò ní ọgbà ẹ̀wọ̀n tó wà.

Oṣù Keje, ọdún 2022 ni wọ̀n fi Baba Ijes̩a si ẹ̀wọ̀n lẹ́yìn tí ilé ẹjọ́ tó n gbọ́ ẹ̀sùn ìfipábánilòpọ̀ sọ pé ó jẹ̀bi esun fifi ipa ba ọmọdé kan lo.

Ijabo to te oniroyin lowo lati enu agbẹjọ́rò kan tó súnmọ́ Baba Ijes̩a, eni tí kò fe dárúkọ ara re ṣàlàyé pé irọ́ tó jìnà sí òótọ́ ní ìròyìn ọ̀hún àti pé Baba Ijes̩a ṣì wà ní ọ̀gbà ẹ̀wọ̀n tó wà.

Ó sọ pé ọjọ́ tí wọ́n gbé ìdájọ́ náà kalẹ̀ ni wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí ní ka ọdún fún un àmọ́ ohun tó dá òun lójú ni pé Baba Ijes̩a kò ní pẹ́ kúrò lọ́gbà ẹ̀wọ̀n.

Ó fi kun un pé pẹ̀lú ọjọ́ àti oṣù tí o ti lò lọ́gbà ẹ̀wọ̀n, kò ní pẹ́ mọ́ tí yoo fi gba ìtúsílẹ̀ kúrò lọ́gbà ẹ̀wọ̀n.

“Tó bá fi máa tó ìparí oṣù Kẹjọ sí oṣù Kẹsàn-án, ó máa kúrò lọ́gbà ẹ̀wọ̀n, ìgbà tó máa lò lẹ́wọ̀n ti fẹ́ parí.”

Ẹ ó rántí pé ní ọdún 2021 ni òṣèré Damilola Adekoya tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Princess fẹ̀sùn kàn pé Baba Ije̩s̩a pe o ṣe aṣemáṣe pẹ̀lú ọmọ tí òun gbà tọ́ nígbà tí ọmọ náà wà ní ọdún mẹ́rìnlá láàárín ọdún 2013 sí 2014.

Ó ní èyí ló mú òun gbé ẹ̀rọ ayàwòrán sínú ilé òun láti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ nígbà tí o fẹ́ ṣe àbẹ̀wò sílé òun lọ́dún 2021, táwọn ọlọ́pàá sì nawọ́ gán an lórí ẹ̀sùn náà.

Láti ìgbà náà ni ilé ẹjọ́ Májísíréètì Eko ti bẹ̀rẹ̀ sí ní gbọ ẹjọ́ náà kí wọ́n tó gbé ìdájọ́ kalẹ̀ lọ́jọ́ Kẹrìnlá, oṣù Keje, ọdún 2022.

Ọjọ́ Kẹrìnlá, oṣù Keje, ọdún 2022 ni Adájọ́ Oluwatoyin Taiwo ti ilé ẹjọ́ tó ń gbọ́ ẹ̀sùn ìfipábánilòpọ̀ ní ìpínlẹ̀ Eko ju u sẹ́wọ̀n ọdún márùn-ún fún ẹ̀sùn bíbá ọmọdé lòpọ̀.

Wọ́n ní ibamu pelu òfin ìwà ọ̀daràn tí ìpínlẹ̀ Eko tọdún 2015.

Bákan náà ni wọ́n ló jẹ̀bi gbígbé ọmọbìnrin náà sórí itan rẹ̀, tó sì ń fi nǹkan ọmọkùnrin rẹ̀ pa á lára lọ́jọ́ Kejìlélógún, oṣù Kẹrin, ọdún 2021.

Ṣùgbọ́n ilé ẹjọ́ ní kò jẹ̀bi ẹ̀sùn fífi kọ́kọ́rọ́ ọkọ̀ rẹ̀ sójú ara ọmọ náà lọ́dún 2013 àti ìgbìyànjú láti bá a lòpọ̀ lọ́jọ́ Kejìlélógún, oṣù Kẹrin, ọdún 2021.

Ìdájọ́ yi yìí kò dùn mọ Baba Ijes̩a nínú èyí tó mu u gba ilé ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn lọ.

Ó bèèrè pé kí ilé ẹjọ́ fagilé ìgbẹ́jọ́ náà àti ẹ̀wọ̀n tí wọ́n dá fún òun.

Agbẹjọ́rò Baba Ijes̩a nígbà náà, Kayode Olabiran sọ pé agbẹjọ́rò ìjọba kò ní ẹ̀rí láti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé oníbàárà òun bá ọmọ náà lòpọ̀ àti pé wọ́n mọ̀ọ́mọ̀ dẹ pàkúté sílẹ̀ fún Baba Ije̩s̩a ni.

Ó sọ nígbà náà pé “òṣèré ni Baba Ije̩s̩a, ìwé ìtàn tí akẹgbẹ́ rẹ̀ Damilola Adekoya pè é sí láti kópa nínú rẹ̀ ló fi ṣeré tí wọ́n sọ di ẹ̀sùn mọ lọ́wọ́.”

Àmọ́ ilé ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn náà sọ pé Baba Ijes̩a jẹ̀bi ẹ̀sùn tí wọ́n fì kàn-án tó sì nílò láti ṣẹ̀wọ̀n ọdún márùn-ún rẹ̀ ni pipe bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n fagile ẹ̀sùn mẹ́ta nínú àwọn ẹ̀sùn márùn-ún tí wọ́n fi si lese.