Ayò̩ abaratíńtín, Priscilla Ojo d’abiyamo̩
Mary Fágbohùn
Osere tiata Iyabo Ojo ti fi tayo tayo kede iwasaye omoomo re, Rakeem Mkambala, ti omobinrin re Priscilla Ojo bi fun oko re ara Tanzanian, Juma Jux.
Tokotaya naa se igbeyawo nibi ti won ti f’ile poti f’ona r’oka ni Osu kerin.
Saaju ni tokotaya oun ti se alabapin ayo naa pelu awon ololufe won lasiko ti Priscilla safihan ikun re.
Iyabo Ojo fi ayo re han ati idunnu jije iya agba, o fi atejade atokanwa lede lori ayelujara.
O kowe pe, “E ki iya agba tuntun nigboro, omoomo mi lo joju ju”.