Àyẹ̀wò ẹ̀jẹ̀ ní Davido kọ́ ló l’ọmọ àmọ́ iléèwé ọ̀fẹ́ l’ọmọ àtìyá ń lọ – Bàbá Davido

Àyẹ̀wò ẹ̀jẹ̀ ni Davido kọ́ ló l’ọmọ àmọ́ iléèwé ọ̀fẹ́ l’ọmọ àtìyá ń lọ – Bàbá Davido

Yínká Àlàbí

Dokita Adedeji Adeleke to jẹ baba gbaju-gbaja olorin igbalode, David Adeleke ti gbogbo eniyan mọ si Davido ti sọrọ soke.
Baba yii ni pẹlu ayẹwo ẹjẹ (DNA) ti awọn ṣe lọna meji lori Aanuoluwapọ ti arabinrin kan loun bi fun Davido.
Dr. Adedeji ni “ gbogbo ayẹwo ẹjẹ mejeeji lawọn ko fun ẹgbọn rẹ ti awọn jọ maa n sọrọ. Onimọ sayẹnsi ni ẹgbọn rẹ naa ti emi ni igbagbọ pe o yẹ ki iru nnkan bẹẹ ye daadaa”.
“Loootọ ni mama Aanuoluwapọ beere fun iranlọwọ ti mo si tẹwọ gba iya ati ọmọ. Mo maa n san owo ile iwe ọmọ pẹlu nnkan tasẹrẹ lori rẹ, bẹẹ ni mo gba iya naa si ile-iwe Fasiti Adeleke. Arabinrin naa si n se daadaa ninu ede Gẹẹsi to n se sugbọn lẹyin ọdun kin-in-ni ni arabinrin naa ko wa mọ, bi o tilẹ jẹ pe aaye si wa fun un to ba de pada. Mo si tun maa n fun un ni aadọta naira losoosu”. Dr. Adeleke tẹsiwaju pe “ iru iranlọwọ to beere ko tilẹ jẹ nnkankan si mi nitori pe ẹgbẹrun mẹta akẹkọọ ti n ko mọ ile ati ọna wọn lo wa lori ẹkọ ọfẹ mi”.
Baba Davido salaye yii ni ile rẹ to wa ni Eko lati le jẹ ki araye mọ pe idile oun ko kọ ọmọ nitori bukata, bi ko se pe awọn ko fẹ ki wọn gbe ọmọ ọba fun ọṣun.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here