Àyájọ́ ọjọ́ Ìsẹ̀ṣe ọdún ìbílẹ̀ kárí ayé

Àyájọ́ ọjọ́ Ìsẹ̀ṣe ọdún ìbílẹ̀ kárí ayé

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé wọ́n ní ń tí oníkálùkù bá ní náà ni yóò fi gbéra rẹ̀ lárúgẹ
Ìṣẹ̀ṣe Day jẹ́ àdájọ́ ọjọ́ àṣà àti ẹ̀sìn táwọn ọmọ Yorùbá tó ń se ẹsin ìbílẹ̀ jákè jádò àgbáyé, máa ń sàmí rẹ̀ ní ọdọọdún.

Lara awọn orilẹede to maa n kopa ninu rẹ yatọ si awọn ipinlẹ to wa lẹyin iwọ oorun guusu Naijiria ni orilẹede Brazil, Portugal ati ilẹ olominira Benin.

Ọjọ Isẹse yii si ni wọn ya sọtọ lati bu ọla fun awọn orisa ati ẹsin ibilẹ lọna ati daabo bo asa ati ohun ajogunba iran Yoruba, ko maa ba parun.

Koda, awọn ipinlẹ kan nilẹ Yoruba bii ipinlẹ Eko, Osun, Oyo ati Ogun si ti ya Ogunjọ osu Kẹjọ ọdọọdun sọtọ gẹgẹ bi ayajọ ọjọ Isẹse.

Bakan naa, awọn ipinlẹ yii ti kede ọjọ Isẹse bii ọjọ isinmi lẹnu isẹ jake jado ipinlẹ koowa wọn.